Hosea ORI 1 1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Hosea, ọmọ Beeri wá, li ọjọ Ussiah, Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi, ọba Israeli. 2 Ibẹrẹ ọ̀rọ Oluwa ti Hosea. OLUWA si wi fun Hosea pe, Lọ, fẹ́ obinrin panṣaga kan fun ara rẹ, ati awọn ọmọ panṣaga: nitoriti ilẹ na ti ṣe panṣaga nla, ti nlọ kuro lọdọ Oluwa. 3 Bẹ̃ni o lọ o si fẹ́ Gomeri ọmọbinrin Diblaimu; tí ó lóyún, tí ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. 4 OLUWA si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Jesreeli; nitori nigba diẹ si i, emi o si gbẹsan ẹ̀jẹ Jesreeli lara ile Jehu, emi o si mu ki ijọba ile Israeli ki o dópin. 5 Yio si ṣe li ọjọ na, li emi o ṣẹ́ ọrun Israeli li afonifoji Jesreeli. 6 O si tun lóyún, o si bí ọmọbinrin kan. Ọlọrun si wi fun u pe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loruhama: nitoriti emi kì yio ṣãnu fun ile Israeli mọ́; ṣugbọn emi o mu wọn kuro patapata. 7 Ṣugbọn emi o ṣãnu fun ile Juda, emi o si fi Oluwa Ọlọrun wọn gbà wọn, emi kì yio fi ọrun, tabi idà, tabi ogun, ẹṣin, tabi ẹlẹṣin gbà wọn. 8 Nigbati o si já Loruhama li ọmu li ọmu, o si yún, o si bí ọmọkunrin kan. 9 Ọlọrun si wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi: nitoriti ẹnyin kì iṣe enia mi, bẹ̃li emi kì yio jẹ Ọlọrun nyin. 10 Ṣugbọn iye awọn ọmọ Israeli yio dabi iyanrìn okun, ti a kò le wọ̀n, bẹ̃li a kò le kà; yio si ṣe, ni ibi ti a ti wi fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o ti wi fun wọn pe, Ọmọ Ọlọrun alãye li ẹnyin iṣe. 11 Nigbana li awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Israeli yio kojọ pọ̀, nwọn o si yàn olori kan fun ara wọn, nwọn o si gòke lati ilẹ na wá: nitori nla yio jẹ ọjọ Jesreeli. ORI 2 1 Ẹ sọ fun awọn arakunrin nyin pe, Ammi; ati fun awọn arabinrin rẹ, Ruhama. . 3 Ki emi ki o má ba bọ́ ọ si ìhoho, emi o si gbe e kalẹ bi li ọjọ́ ti a bí, emi o si sọ ọ di aginju, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a. 4 Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n. 5 Nitoripe iya wọn ti ṣe panṣaga: ẹniti o loyun wọn ṣe ohun itiju: nitoriti o wipe, Emi o tọ̀ awọn ololufẹ mi lẹhin, ti nwọn fun mi li onjẹ mi ati omi mi, irun agutan mi ati ọ̀gbọ mi, ororo mi ati ohun mimu mi. 6 Nitorina, sa wò o, emi o fi ẹgún di ọ̀na rẹ, emi o si mọ odi, ki o má ba ri ipa-ọ̀na rẹ̀. 7 On o si ma tọ̀ awọn ololufẹ rẹ̀ lẹhin, ṣugbọn on kì yio le wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana li on o wipe, Emi o lọ, emi o si pada tọ̀ ọkọ mi iṣaju; nitori nigbana o ha san fun mi ju nisisiyi lọ. 8 Nitoriti kò mọ̀ pe emi fi ọkà, ati ọti-waini, ati ororo fun on, mo si sọ fadakà ati wura rẹ̀ di pupọ̀, ti nwọn pèse fun Baali.
9 Nitorina li emi o ṣe pada, emi o si mu ọkà mi kuro li akokò rẹ̀, ati ọti-waini mi li akokò rẹ̀, emi o si gbà irun agutan mi pada, ati ọ̀gbọ mi ti a fi fun lati bò ìhoho rẹ̀. 10 Njẹ nisisiyi emi o si fi ìwa ifẹkufẹ rẹ̀ hàn li oju awọn ololufẹ rẹ̀, kò si si ẹniti yio gbà a li ọwọ́ mi. 11 Èmi yóò sì mú kí gbogbo ayọ̀ rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀, ọjọ́ àjọ̀dún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, àti gbogbo àjọ̀dún rẹ̀. 12 Emi o si pa àjara rẹ̀ run, ati igi ọpọtọ rẹ̀, eyiti o ti wipe, Wọnyi li ère mi ti awọn olufẹ mi fi fun mi: emi o si sọ wọn di igbó, awọn ẹranko igbẹ yio si jẹ wọn. 13 Emi o si bẹ̀ ọ wò li ọjọ́ Baalimu, ninu eyiti o sun turari fun wọn, ti o si fi oruka-etí rẹ̀ ati ohun ọṣọ́ rẹ̀ ṣe ara rẹ̀ li ọṣọ́, ti o si tọ̀ awọn ololufẹ rẹ̀ lẹhin, o si gbagbe mi, li Oluwa wi. 14 Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mú u wá si ijù, emi o si sọ̀rọ itunu fun u. 15 Emi o si fi ọgba-àjara rẹ̀ fun u lati ibẹ̀ wá, ati afonifoji Akori fun ilẹkun ireti: on o si ma kọrin nibẹ̀, gẹgẹ bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ́ ti o ti ilẹ Egipti jade wá. 16 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ti iwọ o pè mi ni Iṣi; emi kì yio si pè mi ni Baali mọ. 17 Nitoripe emi o mu orukọ Baalimu kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si ranti wọn mọ li orukọ wọn. 18 Ati li ọjọ na li emi o ba awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ ojuọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ dá majẹmu fun wọn: emi o si ṣẹ́ ọrun, idà, ati ogun kuro lori ilẹ, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu. 19 Emi o si fẹ ọ fun mi lailai; lõtọ, emi o fẹ́ ọ fun mi li ododo, ati li idajọ, ati ninu ãnu, ati ninu ãnu. 20 Emi o si fẹ́ ọ fun mi li otitọ: iwọ o si mọ̀ Oluwa. 21 Yio si ṣe li ọjọ na, Emi o gbọ́, li Oluwa wi, Emi o gbọ́ ọrun, nwọn o si gbọ́ aiye; 22 Ilẹ yio si gbọ́ ọkà, ati ọti-waini, ati ororo; nwọn o si gbọ́ ti Jesreeli. 23 Emi o si gbìn i fun mi lori ilẹ; emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Ẹnyin li enia mi; nwọn o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi. ORI 3 1 OLUWA si wi fun mi pe, Lọ sibẹ, fẹ obinrin olufẹ si ọ̀rẹ́ rẹ̀, sibẹ panṣaga obinrin, gẹgẹ bi ifẹ OLUWA si awọn ọmọ Israeli, ti o nreti ọlọrun miran, ti o si fẹ agolo ọti-waini. 2 Bẹ̃ni mo rà a fun mi ni ìwọn fadaka mẹdogun, ati fun homeri barle kan, ati àbọ homeri barle kan. 3 Emi si wi fun u pe, Iwọ o joko fun mi li ọjọ́ pipọ; iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, bẹ̃li iwọ ki yio si ṣe fun ẹlomiran: bẹ̃li emi o si ri fun ọ pẹlu. 4 Nitoriti awọn ọmọ Israeli yio gbe li ọjọ pipọ li aini ọba, ati laini ọmọ-alade, ati laini ẹbọ, ati laini ere, ati laini efodu, ati li aini terafimu. 5 Nigbana li awọn ọmọ Israeli yio yipada, nwọn o si wá Oluwa Ọlọrun wọn, ati Dafidi ọba wọn; nwọn o si bẹ̀ru Oluwa ati ore rẹ̀ li ọjọ ikẹhin. ORI 4 1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọmọ Israeli: nitoriti Oluwa ni ẹjọ́ pẹlu awọn ara ilẹ na, nitoriti kò si otitọ, tabi ãnu, tabi ìmọ Ọlọrun ni ilẹ na. .