Skip to main content

Yoruba - The Book of Prophet Amos

Page 1

Amosi ORI 1 1 Ọ̀RỌ Amosi, ti o wà ninu awọn darandaran Tekoa, ti o ri niti Israeli li ọjọ Ussiah ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli, li ọdun meji ṣiwaju ìṣẹlẹ na. 2 O si wipe, Oluwa yio bú lati Sioni wá, yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ lati Jerusalemu wá; Ibugbe awọn darandaran yio si ṣọ̀fọ, ori Karmeli yio si rọ. 3 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi ijiya rẹ̀ pada; nitoriti nwọn ti fi irin ipakà pa Gileadi: 4 Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi run. 5 Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku pẹ̀lú,n óo sì gé àwọn tí ń gbé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Afeni kúrò,ati ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní ilé Edeni.Àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní Kiri,OLUWA ní. 6 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti nwọn kó gbogbo igbekun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ. 7 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara ogiri Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ run. 8 Emi o si ke awọn ara ilu kuro ni Aṣdodu, ati ẹniti o di ọpá alade mu ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni: iyokù awọn Filistini yio si ṣègbé, li Oluwa Ọlọrun wi. 9 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta Tire, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti nwọn fi gbogbo igbekun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin. 10 Ṣugbọn emi o rán iná kan sara ogiri Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ run. 11 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si kọ̀ ãnu gbogbo silẹ, ibinu rẹ̀ si fàya lailai, o si pa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. 12 Ṣugbọn emi o rán iná si Temani, ti yio jo ãfin Bosra run. 13 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nítorí pé wọ́n ta àwọn aboyún Gileadi ya, kí wọ́n lè mú kí ààlà wọn gbilẹ̀. 14 Ṣugbọn emi o da iná ni gbogbo Rabba, yio si jo ãfin rẹ̀ run, pẹlu ariwo li ọjọ ogun, pẹlu ẹfufu lile li ọjọ ìji: 15 Ati ọba wọn yio lọ si igbekun, on ati awọn ijoye rẹ̀, li Oluwa wi. ORI 2 1 BAYI li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti o sun egungun ọba Edomu di orombo. 2 Ṣugbọn emi o rán iná si Moabu, yio si jó ãfin Kerioti run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu ariwo, ati pẹlu iró ipè. 3 Emi o si ke onidajọ kuro lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo awọn ijoye rẹ̀ pẹlu rẹ̀, li Oluwa wi. 4 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, ati irọ́ wọn mu wọn ṣìna, eyiti awọn baba wọn ti rìn. 5 Ṣugbọn emi o rán iná si Juda, yio si jo ãfin Jerusalemu run.

6 Bayi li Oluwa wi; Nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì yio yi iyà rẹ̀ pada; nitoriti nwọn ta olododo fun fadaka, ati talaka fun bàta-meji; 7. Ẹniti o ma rẹra si erupẹ ilẹ li ori awọn talakà, ti o si yà li ọ̀na awọn ọlọkàn tutù: ati ọkunrin ati baba rẹ̀ yio wọle tọ̀ wundia kanna lọ, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ. 8 Wọ́n sì dùbúlẹ̀ sórí aṣọ tí wọ́n fi lélẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, wọ́n sì mu wáìnì ẹni tí a dá lẹ́bi nínú ilé òrìṣà wọn. 9 Ṣugbọn mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn, ẹni tí gíga rẹ̀ rí bí igi kedari, ó sì lágbára bí igi oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati gbòngbo rẹ̀ nisalẹ. 10 Emi si mú nyin gòke lati ilẹ Egipti wá pẹlu, mo si mu nyin la aginjù li ogoji ọdún lọ, lati gbà ilẹ awọn Amori. 11 Emi si gbe ninu awọn ọmọ nyin dide fun woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin fun Nasiri. Bẹ̃li kò ha ri bẹ̃, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. 12 Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasiri li ọti-waini mu; o si paṣẹ fun awọn woli, wipe, Máṣe sọtẹlẹ. 13 Kiyesi i, a tẹ̀ mi labẹ rẹ, bi a ti tẹ̀ kẹkẹ́ ti o kún fun ití. 14 Nítorí náà, àsálà yóò ṣègbé lọ́wọ́ ẹni tí ó yára, alágbára kì yóò sì fún agbára rẹ̀ lókun, bẹ́ẹ̀ ni alágbára kì yóò gba ara rẹ̀ là. 15 Bẹ̃ni ẹniti o di ọrun kì yio duro; ati ẹniti o yara kì yio gba ara rẹ̀ là: bẹ̃li ẹniti o gùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là. 16 Ẹniti o si ṣe akikanju ninu awọn alagbara yio salọ nihoho li ọjọ na, li Oluwa wi. ORI 3 1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ sí yín, ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì, sí gbogbo ìdílé tí mo mú gòkè wá láti ilẹ̀ Éjíbítì wá pé: 2 Iwọ nikanṣoṣo li emi mọ̀ ninu gbogbo idile aiye: nitorina li emi o ṣe jẹ nyin niya nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin. 3 Ǹjẹ́ ẹni méjì lè jọ rìn bí kò ṣe pé wọ́n fẹ́? 4 Kiniun yio ha ké ramúramù ninu igbo, nigbati kò ni ohun ọdẹ? Ẹgbọrọ kiniun yio ha kigbe lati inu iho rẹ̀ wá, bi kò ba mu nkan bi? 5 Ẹiyẹ ha le bọ́ sinu okùn kan lori ilẹ, nibiti okùn kò si fun u? ẹnikan ha le mu ikẹkun kuro lori ilẹ, ti kò si mu nkankan rara? 6 A ha le fun ipè ni ilu, ki awọn enia ki o má bẹ̀ru bi? ibi yio ha wà ni ilu kan, ti Oluwa kò si ṣe e bi? 7 Nitõtọ Oluwa Ọlọrun kì yio ṣe nkan, bikoṣepe o fi aṣiri rẹ̀ hàn fun awọn iranṣẹ rẹ̀ woli. 8 Kiniun ti ke, tani kì yio bẹ̀ru? Oluwa Ọlọrun ti sọ, tani o le sọtẹlẹ? 9 Ẹ tẹ̀wé jáde ní ààfin Áṣídódì,àti ní ààfin ní ilẹ̀ Éjíbítì,kí ẹ sì wí pé, ‘Ẹ kó ara yín jọ sí orí òkè Samáríà,kí ẹ sì wo ìdàrúdàpọ̀ ńlá ní àárín rẹ̀,àti àwọn ìnilára ní àárín rẹ̀. 10 Nitoriti nwọn kò mọ̀ ati ṣe rere, li Oluwa wi, ti nwọn kó ìwa-ipa ati ole jija jọ sinu ãfin wọn. 11 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eta yio si wa yi ilẹ na ká; on o si sọ agbara rẹ kalẹ kuro lọdọ rẹ, a o si ba awọn ãfin rẹ jẹ. 12 Bayi li Oluwa wi; Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ti í mú ẹsẹ̀ méjì, tàbí etí etí kan jáde lẹ́nu kìnnìún; bẹ̃li a o kó awọn ọmọ Israeli jade ti ngbé Samaria ni igun ibùsùn, ati ni Damasku ninu akete. 13. Ẹ gbọ́, ki ẹ si jẹri ni ile Jakobu, li Oluwa Ọlọrun, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi. 14 Pe li ọjọ́ na ti emi o bẹ̀ irekọja Israeli wò lara rẹ̀, emi o si bẹ̀ awọn pẹpẹ Beteli wò pẹlu: a o si ke iwo pẹpẹ na kuro, nwọn o si ṣubu lulẹ.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of Prophet Amos by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu