Òwe ORI 1 1 Òwe Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli; 2 Lati mọ̀ ọgbọ́n ati ẹkọ́; lati mọ awọn ọrọ oye; 3 Lati gba ẹkọ́ ọgbọ́n, idajọ, ati idajọ, ati otitọ; 4 Lati fi arekereke fun awọn òpe, fun ọdọmọkunrin ni ìmọ ati oye. 5 Ọlọgbọ́n enia yio gbọ́, yio si ma pọ̀ si i li ẹkọ; enia oye yio si gba ìmọ̀ ọgbọ́n; 6 Lati mọ òwe, ati itumọ̀; ọ̀rọ awọn ọlọgbọ́n, ati ọ̀rọ òkunkun wọn. 7 Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ìmọ: ṣugbọn awọn aṣiwere gàn ọgbọ́n ati ẹkọ́. 8 Ọmọ mi, gbọ́ ẹkọ́ baba rẹ, má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ. 9 Nitoripe nwọn o jẹ ohun ọṣọ́ ore-ọfẹ si ori rẹ, ati ẹ̀wọn yi ọrùn rẹ ka. 10 Ọmọ mi, bi awọn ẹlẹṣẹ ba tàn ọ, máṣe gbà. 11 Bi nwọn ba wipe, Wa pẹlu wa, ẹ jẹ ki a ba dè ẹ̀jẹ, ẹ jẹ ki a ba ni ìkọkọ fun alaiṣẹ̀ lainidi. 12 Jẹ ki a gbe wọn mì lãye bi isà-okú; ati odidi, bi awọn ti o sọkalẹ lọ sinu iho. 13 Awa o ri gbogbo nkan iyebiye, awa o fi ikogun kún ile wa. 14 Fi ipín rẹ ṣẹ́ lãrin wa; e je ki gbogbo wa ni apamọwọ kan: 15 Ọmọ mi, máṣe ba wọn rìn li ọ̀na; pa ẹsẹ rẹ mọ́ kuro ni ipa-ọ̀na wọn: 16 Nitoripe ẹsẹ wọn sure si ibi, nwọn si yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ. 17 Nitõtọ lasan li a nà àwọ̀n si oju ẹiyẹ eyikeyi. 18 Nwọn si ba dè ẹ̀jẹ ara wọn; wọ́n sápamọ́ ní ìkọ̀kọ̀ fún ẹ̀mí ara wọn. 19 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà gbogbo ẹni tí ó ń ṣe ojúkòkòrò èrè; ti o gba ẹmi awọn oniwun rẹ lọ. 20 Ọgbọ́n kigbe lode; ó ń fọhùn ní ìgboro. 21 O kigbe ni ibi nla apejọ, ni ẹnu-ọ̀na ibode: ni ilu li o sọ ọ̀rọ rẹ̀, wipe, 22 Yóò ti pẹ́ tó, ẹ̀yin òpè, tí ẹ̀yin yóò fi fẹ́ àìmọ́? ati awọn ẹlẹgàn ṣe inudidun si ẹgan wọn, ati awọn aṣiwere si korira ìmọ? 23. Ẹ yipada si ibawi mi: kiyesi i, emi o tú ẹmi mi si nyin, emi o sọ ọ̀rọ mi di mimọ̀ fun nyin. 24 Nitoripe emi ti pè, ẹnyin si kọ̀; Mo ti nà ọwọ́ mi, kò sì sí ẹni tí a kà sí; 25 Ṣugbọn ẹnyin ti sọ gbogbo ìmọ mi di asan, ẹ kò si fẹ ibawi mi. 26 Emi pẹlu yio si rẹrin nitori ibi nyin; Emi o ṣe ẹlẹyà nigbati ẹ̀ru nyin ba de; 27 Nigbati ẹ̀ru nyin ba de bi idahoro, ati iparun nyin ba de bi ìji; nígbà tí ìdààmú àti ìdààmú bá dé bá yín. 28 Nigbana ni nwọn o kepè mi, ṣugbọn emi kì yio dahùn; nwọn o wá mi ni kutukutu, ṣugbọn nwọn kì yio ri mi. 29 Nitoriti nwọn korira ìmọ, nwọn kò si yàn ibẹ̀ru Oluwa. 30 Nwọn kò fẹ ìmọ mi: nwọn gàn gbogbo ibawi mi. 31 Nitorina nwọn o jẹ ninu eso ọ̀na ara wọn, nwọn o si kún fun èro ara wọn. 32 Nítorí pé ìyípadà àwọn òpè yóò pa wọ́n,àti pé àlàáfíà àwọn òmùgọ̀ yóò pa wọ́n run. 33 Ṣugbọn ẹniti o gbọ́ ti emi yio ma gbe li ailewu, yio si dakẹ ninu ibẹru ibi.
ORI 2 1 Ọmọ mi, bi iwọ ba gbà ọ̀rọ mi, ti iwọ o si fi ofin mi pamọ́ lọdọ rẹ; 2 Ki iwọ ki o dẹ eti rẹ si ọgbọ́n, ki o si fi aiya rẹ si oye; 3 Nitõtọ, bi iwọ ba kigbe lẹhin ìmọ, ti iwọ si gbe ohùn rẹ soke fun oye; 4 Bi iwọ ba wá a bi fadaka, ti iwọ si wá a kiri bi iṣura ti a pamọ́; 5 Nigbana li ẹnyin o mọ̀ ibẹ̀ru Oluwa, iwọ o si ri ìmọ Ọlọrun. 6 Nitoripe Oluwa li o fi ọgbọ́n funni: ẹnu rẹ̀ li ìmọ ati oye ti njade. 7 O fi ọgbọ́n ti o yè kalẹ fun olododo: on li apata fun awọn ti nrin dede. 8 O pa ipa-ọ̀na idajọ mọ́, o si pa ọ̀na awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́. 9 Nigbana li o ye ododo, ati idajọ, ati otitọ; nitõtọ, gbogbo ona rere. 10 Nigbati ọgbọ́n ba wọ̀ inu rẹ lọ, ti ìmọ si dùn si ọkàn rẹ; 11 Ọgbọ́n yio pa ọ mọ́, oye yio pa ọ mọ́. 12 Lati gbà ọ lọwọ ọ̀na enia buburu, lọwọ ẹniti nsọ̀rọ arekereke; 13 Ti o fi ipa-ọ̀na iduro-ṣinṣin silẹ, lati ma rìn li ọ̀na òkunkun; 14 Awọn ẹniti nyọ̀ lati ṣe buburu, ti nwọn si ṣe inu-didùn si arekereke enia buburu; 15 Awọn ọ̀na ẹniti o wọ̀, ti nwọn si yipadà li ipa-ọ̀na wọn. 16 Lati gbà ọ lọwọ ajeji obinrin, ani lọwọ alejò ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe iyin; 17 Ẹniti o kọ̀ amọ̀na igba ewe rẹ̀ silẹ, ti o si gbagbe majẹmu Ọlọrun rẹ̀. 18 Nitoripe ile rẹ̀ fà si ikú, ati ipa-ọ̀na rẹ̀ sọdọ okú. 19 Ẹniti o tọ̀ ọ wá kò tun pada, bẹ̃ni nwọn kò di ipa-ọ̀na ìye mu. 20 Ki iwọ ki o le ma rìn li ọ̀na enia rere, ki iwọ ki o si ma pa ipa-ọ̀na awọn olododo mọ́. 21 Nitoripe awọn olododo ni yio ma gbe ilẹ na, ati awọn ti o pé ni yio ma gbe inu rẹ̀. 22 Ṣugbọn awọn enia buburu li a o ke kuro lori ilẹ, ati awọn olurekọja li a o fà tu kuro ninu rẹ̀. ORI 3 1 Ọmọ mi, máṣe gbagbe ofin mi; ṣugbọn jẹ ki aiya rẹ pa ofin mi mọ́. 2 Nitoripe ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia, ni nwọn o fi kún ọ. 3 Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o kọ̀ ọ: dè wọn mọ́ ọrùn rẹ; kọ wọn sori tabili ọkàn rẹ. 4 Bẹ̃ni iwọ o ri ojurere ati oye rere li oju Ọlọrun ati enia. 5 Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; má si ṣe fi ara tì oye ara rẹ. 6 Mọ̀ ọ li ọ̀na rẹ gbogbo, on o si ma tọ́ ipa-ọ̀na rẹ. 7 Máṣe gbọ́n li oju ara rẹ: bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi. 8 Yóo jẹ́ ìlera fún ìwo rẹ,yóo sì jẹ́ ọ̀rá fún egungun rẹ. 9 Fi ọ̀wọ̀ fun Oluwa pẹlu ohun ini rẹ, ati pẹlu akọso gbogbo ibisi rẹ. 10 Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati ifọnti rẹ yio si tú jade fun ọti-waini titun. 11 Ọmọ mi, má ṣe gàn ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe rẹ̀ fun ibawi rẹ̀: