Àánú Ọlọ́run àti Ènìyàn
Olúwa jẹ́ aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ó lọ́ra láti bínú, ó sì ní àánú púpọ̀. Sáàmù 103:8 Nítorí náà, ẹ jẹ́ aláàánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín pẹ̀lú ti jẹ́ aláàánú. Lúùkù 6:36
Ìwé Píntátéùkì Nígbà tí ó ń lọ́ra, àwọn ọkùnrin náà gbá a mú, àti ọwọ́ aya rẹ̀, àti ọwọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì; Olúwa ṣàánú fún un. Wọ́n sì mú un jáde, wọ́n sì fi í síta ìlú náà. Jẹ́nẹ́sísì 19:16 Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúrere rẹ ní ojú rẹ, ìwọ sì ti gbé àánú rẹ ga, èyí tí ìwọ ti fi hàn mí nípa gbígbà ẹ̀mí mi là; èmi kò sì le sá lọ sí òkè, kí ibi má baà bá mi, kí èmi sì kú. Jẹ́nẹ́sísì 19:19 Ó sì wí pé, “Olùbùkún ni fún Olúwa Ọlọ́run Ábúráhámù ọ̀gá mi, ẹni tí kò fi àánú àti òtítọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún ọ̀gá mi. Bí mo ti wà ní ọ̀nà, Olúwa tọ́ mi lọ sí ilé àwọn arákùnrin ọ̀gá mi.” Jẹ́nẹ́sísì 24:27 Èmi kò yẹ fún èyí tí ó kéré jùlọ nínú gbogbo àánú àti òtítọ́ tí o ti fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ; nítorí pé mo fi ọ̀pá mi kọjá Jordani yìí, mo sì ti di ẹgbẹ́ méjì báyìí. Jẹ́nẹ́sísì 32:10 Ṣùgbọ́n Olúwa wà pẹ̀lú Jósẹ́fù, ó sì fi àánú hàn sí i, ó sì fún un ní ojúrere ní ojú olùṣọ́ ẹ̀wọ̀n náà. Jẹ́nẹ́sísì 39:21 Kí Ọlọ́run Olódùmarè sì fún yín ní àánú níwájú ọkùnrin náà, kí ó lè rán arákùnrin yín kejì àti Benjamini lọ. Bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, mo pàdánù. Jẹ́nẹ́sísì 43:14 Nínú àánú rẹ ni ìwọ ti ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà padà: ìwọ ti fi agbára rẹ tọ́ wọn lọ sí ibùgbé mímọ́ rẹ. Ẹ́ kísódù 15:13 Ati fifi aanu han si ẹgbẹẹgbẹrun awọn ti o fẹran mi, ti wọn si n pa ofin mi mọ. Ẹ́ kísódù 20:6 Kí o sì fi wúrà mímọ́ ṣe ìtẹ́ àánú: ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀. Ìwọ yóò sì fi wúrà ṣe kérúbù méjì, tí a fi iṣẹ́ lílù ṣe, ní ìpẹ̀kun méjèèjì ìtẹ́ àánú náà. Kí o sì ṣe kérúbù kan ní ìpẹ̀kun kan, kí o sì ṣe kérúbù kejì ní ìpẹ̀kun kejì. Pẹ̀lú ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn kérúbù náà ní ìpẹ̀kun méjèèjì rẹ̀. Àwọn kérúbù yóò na ìyẹ́ wọn sókè sí òkè, wọn yóò sì fi ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú náà, ojú wọn yóò sì kọjú sí ara wọn; ojú àwọn kérúbù yóò kọjú sí ìtẹ́ àánú náà. Kí o sì gbé ìtẹ́ àánú náà sí orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí tí èmi yóò fi fún ọ sí inú àpótí náà. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti pàdé rẹ, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ láti orí ìtẹ́ àánú, láti àárín àwọn kérúbù méjì tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí, nípa gbogbo ohun tí èmi yóò fún ọ ní àṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ́ kísódù 25: 17-22 Kí o sì gbé ìbòrí àánú náà sórí àpótí ẹ̀rí ní ibi mímọ́ jùlọ. Ẹ́ kísódù 26:34 Kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú aṣọ ìbòjú tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí ẹ̀rí, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí ẹ̀rí, níbi tí èmi yóò ti pàdé rẹ. Ẹ́ kísódù 30:6 Àgọ́ àjọ, àti àpótí ẹ̀rí, àti ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà. Ẹ́ kísódù 31:7