Episteli kini ti Johannu ORI 1 1 Eyi ti o ti wà li àtetekọṣe, ti awa ti gbọ́, ti awa ti fi oju wa ri, ti awa ti wò, ti a si ti di ọwọ́ wa mu, ti Ọ̀rọ ìye; 2 (Nítorí ìyè náà farahàn, àwa sì ti rí i, a sì jẹ́rìí, a sì fi ìyè àìnípẹ̀kun hàn yín, tí ó ti wà lọ́dọ̀ Baba, tí ó sì farahàn fún wa;) 3 Eyi ti awa ti ri, ti a si ti gbọ́ li awa nsọ fun nyin, ki ẹnyin ki o le ni ìrẹpọ pẹlu wa: nitõtọ ìdapọ wa mbẹ pẹlu Baba, ati pẹlu Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi. 4 Ati nkan wọnyi li awa si kọwe si nyin, ki ayọ̀ nyin ki o le kún. 5 Njẹ eyi li ọ̀rọ na ti awa ti gbọ́ lati ọdọ rẹ̀ wá, ti awa si nsọ fun nyin pe, imọlẹ li Ọlọrun, kò si si òkunkun ninu rẹ̀ rara. 6 Bí àwa bá sọ pé a ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, tí a sì ń rìn nínú òkùnkùn, àwa purọ́, a kò sì ṣe òtítọ́. 7 Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òun ti wà nínú ìmọ́lẹ̀, àwa ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo. 8 Bí a bá sọ pé a kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tan ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa. 9 Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ àti olódodo ni òun láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí ó sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo. 10 Bí a bá sọ pé a kò dẹ́ṣẹ̀, àwa ń sọ ọ́ di èké, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa. ORI 2 1 Ẹ̀yin ọmọ mi, nkan wọnyi ni mo kọ si nyin, ki ẹnyin ki o máṣe ṣẹ̀. Bi ẹnikẹni ba si dẹṣẹ, awa ni alagbawi lọdọ Baba, Jesu Kristi olododo: 2 Òun sì ni ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa: kì í sì í ṣe tiwa nìkan, ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé pẹ̀lú. 3 Ati nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mọ̀ ọ, bi awa ba pa ofin rẹ̀ mọ́. 4 Ẹniti o ba wipe, Emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀. 5 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́, lara rẹ̀ li a ti sọ ifẹ Ọlọrun di pipé: nipa eyi li awa mọ̀ pe awa mbẹ ninu rẹ̀. 6 Ẹniti o ba wipe on ngbé inu rẹ̀, on li o yẹ ki on ki o mã rìn bẹ̃ gẹgẹ bi on ti rìn. 7 Ará, kì í ṣe òfin titun ni mò ń kọ sí yín, bí kò ṣe òfin àtijọ́ tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. 8 Lẹẹkansi, ofin titun kan ni mo nkọwe si nyin, eyiti o jẹ otitọ ninu rẹ ati ninu nyin: nitoriti òkunkun ti kọja, ati imọlẹ otitọ ti nmọlẹ nisisiyi. 9 Ẹniti o ba wipe on mbẹ ninu imọlẹ, ti o si korira arakunrin rẹ̀, o wà li òkunkun titi di isisiyi. 10 Ẹniti o ba fẹ arakunrin rẹ̀ ngbé inu imọlẹ, kò si si ohun ikọsẹ ninu rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn,ó sì ń rìn nínú òkùnkùn,kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí òkùnkùn náà ti fọ́ ojú rẹ̀.
12 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin ọmọ mi, nitoriti a dari ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin nitori orukọ rẹ̀. 13 Emi nkọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin ti ṣẹgun ẹni buburu nì. Emi nkọwe si nyin, awọn ọmọde, nitoriti ẹnyin ti mọ Baba. 14 Emi kọwe si nyin, ẹnyin baba, nitoriti ẹnyin ti mọ̀ ẹniti o wà li àtetekọṣe. Emi kọwe si nyin, ẹnyin ọdọmọkunrin, nitoriti ẹnyin li alagbara, ati pe ọ̀rọ Ọlọrun ngbé inu nyin, ẹnyin si ti ṣẹgun ẹni buburu nì. 15 Ẹ máṣe fẹ́ràn aiye, tabi ohun ti mbẹ ninu aiye. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí ninu rẹ̀. 16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú, àti ìgbéraga ìyè, kì í ṣe ti Baba, bí kò ṣe ti ayé. 17. Ayé si nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yio duro lailai. 18 Ẹnyin ọmọ, igba ikẹhin li eyi: ati bi ẹnyin ti gbọ́ pe Aṣodisi-Kristi mbọ̀wá, ani nisisiyi Aṣodisi-Kristi pupọ̀ li o wà; nipa eyiti a mọ pe o jẹ akoko ikẹhin. 19 Nwọn jade kuro lọdọ wa, ṣugbọn nwọn kì iṣe ti wa; nitoriti nwọn iba ṣe ti wa, nitõtọ nwọn iba ba wa duro: ṣugbọn nwọn jade lọ, ki a le fi wọn hàn pe kì iṣe gbogbo wọn. 20 Ṣugbọn ẹnyin ni ijẹ kan lati ọdọ Ẹni-Mimọ́ wá, ẹnyin si mọ̀ ohun gbogbo. 21 Emi ko kọwe si nyin nitoriti ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ti o ti inu otitọ wá. 22 Ta ni òpùrọ́ bí kò ṣe ẹni tí ó sẹ́ pé Jésù ni Kristi náà? Aṣodisi-Kristi ni, ẹniti o sẹ Baba ati Ọmọ. 23 Ẹnikẹni ti o ba sẹ́ Ọmọ, on na kò ni Baba: (ṣugbọn ẹniti o ba jẹwọ Ọmọ ni o ni Baba pẹlu. 24 Nitorina ẹ jẹ ki eyini ki o mã gbé inu nyin, eyiti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe. Bi ohun ti ẹnyin ti gbọ́ li àtetekọṣe ba duro ninu nyin, ẹnyin pẹlu yio si duro ninu Ọmọ, ati ninu Baba. 25 Èyí sì ni ìlérí tí ó ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun. 26 Nkan wọnyi ni mo kọwe si nyin niti awọn ti ntàn nyin jẹ. 27 Ṣùgbọ́n òróró tí ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ rẹ̀ ń gbé inú yín, ẹ kò sì nílò kí ẹnikẹ́ni kọ yín: ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìfòróróróyàn kan náà ti kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí ó sì jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe irọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ni. nyin, ki enyin ki o ma gbe inu re. 28 Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ mi, ẹ mã gbe inu rẹ̀; pé nígbà tí ó bá farahàn, kí á lè ní ìgboyà, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ nígbà dídé rẹ̀. 29 Bi ẹnyin ba mọ̀ pe olododo li on, ẹnyin mọ̀ pe olukuluku ẹniti nṣe ododo, a ti ipa rẹ̀ bi. ORI 3 1 Kiyesi i, iru ifẹ ti Baba fi fun wa, ki a le ma pè wa ni Ọmọ Ọlọrun: nitorina ni aiye kò mọ̀ wa, nitoriti kò mọ̀ ọ. 2 Olufẹ, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe nisisiyi, a kò si tii farahàn bi awa ti yio jẹ: ṣugbọn awa mọ̀ pe, nigbati on ba farahàn, awa o dabi rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i bí ó ti rí. 3 Ati olukuluku ẹniti o ni ireti yi ninu rẹ̀, a wẹ̀ ara rẹ̀ mọ́, gẹgẹ bi on ti mọ́. 4 Ẹnikẹni ti o ba ṣẹ̀, o rú ofin pẹlu: nitori ẹ̀ṣẹ ni irekọja ofin. 5 Ẹ̀yin sì mọ̀ pé ó farahàn láti mú ẹ̀ṣẹ̀ wa lọ; kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀. 6 Ẹnikẹni ti o ba ngbe inu rẹ̀ kì yio dẹṣẹ: ẹnikẹni ti o ba ṣẹ̀ kò ri i, bẹ̃ni kò si mọ̀ ọ. 7 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni ki o tàn nyin: ẹniti o nṣe ododo, olododo ni, ani bi on ti ṣe olododo.