Skip to main content

Yoruba - The Book of Psalms

Page 1

Psalmu ORI 1 1 Ibukún ni fun ọkunrin na ti kò rìn ninu ìmọ awọn enia buburu, ti kò duro li ọ̀na awọn ẹlẹṣẹ, ti kò si joko ni ibujoko awọn ẹlẹgàn. 2 Ṣugbọn inu-didùn rẹ̀ mbẹ ninu ofin Oluwa; ati ninu ofin rẹ̀ li o nṣe àṣàrò lọsan ati loru. 3 On o si dabi igi ti a gbìn si ẹba odò omi, ti nso eso rẹ̀ li akokò rẹ̀; ewe rẹ̀ pẹlu kì yio rọ; ati ohunkohun ti o ba ṣe yoo ṣe rere. 4 Awọn enia buburu kò ri bẹ̃: ṣugbọn nwọn dabi iyangbo ti afẹfẹ nfẹ lọ. 5 Nitorina awọn alaiwa-bi-Ọlọrun kì yio duro ni idajọ, bẹ̃li awọn ẹlẹṣẹ kì yio duro ninu ijọ awọn olododo. 6 Nitoripe Oluwa mọ̀ ọ̀na awọn olododo: ṣugbọn ọ̀na awọn enia buburu ni yio ṣegbe. ORI 2 1 Ẽṣe ti awọn keferi fi binu, ti awọn enia si nrò ohun asan? 2 Awọn ọba aiye dide, awọn ijoye si gbìmọ pọ̀ si Oluwa, ati si ẹni-àmi-ororo rẹ̀, wipe, 3 Jẹ́ kí á já ìdè wọn,kí a sì sọ okùn wọn kúrò lọ́dọ̀ wa. 4 Ẹniti o joko li ọrun yio rẹrin: Oluwa yio fi wọn ṣẹsin. 5 Nígbà náà ni yóò bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ìbínú rẹ̀,yóò sì mú wọn bínú nínú ìbínú rẹ̀ kíkan. 6 Sibẹ emi ti fi ọba mi le ori òke mimọ́ mi ti Sioni. 7 Emi o kede aṣẹ na: Oluwa ti wi fun mi pe, Iwọ li Ọmọ mi; loni ni mo bi ọ. 8 Bère lọwọ mi, emi o si fi awọn keferi fun ọ ni iní rẹ, ati awọn ipẹkun aiye fun iní rẹ. 9 Iwọ o fi ọpá irin fọ́ wọn; ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀kòkò. 10 Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n, ẹnyin ọba: ki a si kọ́ nyin, ẹnyin onidajọ aiye. 11 Ẹ fi ẹ̀ru sin Oluwa, ẹ si yọ̀ pẹlu ìwariri. 12 Fi ẹnu ko Ọmọkunrin li ẹnu, ki o má ba binu, ẹ si ṣegbé li ọ̀na, nigbati ibinu rẹ̀ ba rú diẹ. Ibukún ni fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. ORI 3 1 (ORIN DAFIDI ti Dafidi, nigbati o sa fun Absalomu, ọmọ rẹ̀.) OLUWA, bawo ni nwọn ti pọ̀ si ti awọn ti nyọ mi lẹnu! ọpọ li awọn ti o dide si mi. 2 Ọ̀ pọlọpọ li ẹniti nwi niti ọkàn mi pe, Kò si iranlọwọ fun u ninu Ọlọrun. Sela. 3 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi, ati eniti o gbe ori mi soke. 4 Emi fi ohùn mi kigbe pè Oluwa, o si gbohun mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá. Sela. 5 Mo dùbúlẹ̀, mo sì sùn; Mo ji; nítorí Yáhwè gbá mí ró. 6 Emi kì yio bẹ̀ru ẹgbarun enia, ti o ti dojukọ mi yika. 7 Dide, Oluwa; gbà mi, Ọlọrun mi: nitoriti iwọ ti lu gbogbo awọn ọta mi li egungun ẹ̀rẹkẹ; iwọ ti ṣẹ́ ehin awọn enia buburu. 8 Ti Oluwa ni igbala: ibukún rẹ mbẹ lara awọn enia rẹ. Sela.

ORI 4 1 (Si olori akọrin lori Neginoti, Psalmu Dafidi.)Gbọ mi nigbati mo ba nkepè, Ọlọrun ododo mi: iwọ ti sọ mi di nla nigbati mo wà ninu ipọnju; ṣãnu fun mi, ki o si gbọ́ adura mi. 2 Ẹnyin ọmọ enia, yio ti pẹ to ti ẹnyin o yi ogo mi pada si itiju? bawo ni iwọ o ti fẹ asan pẹ to, ti ẹ o si ma wa awin? Sela. 3 Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ pé OLUWA ti ya ẹni tí ó jẹ́ olódodo sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀,OLUWA yóo gbọ́ nígbà tí mo bá ké pè é. 4 Duro li ẹ̀ru, má si ṣe ṣẹ̀: ba ọkàn ara rẹ sọ̀rọ lori akete rẹ, ki o si duro jẹ. Sela. 5 Ẹ ru ẹbọ ododo, ki ẹ si gbẹkẹle Oluwa. 6 Ọ̀pọlọpọ li o nwipe, Tani yio fi ohun rere kan hàn wa? OLUWA, gbé ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sókè sí wa lára. 7 Iwọ ti fi ayọ̀ si mi li aiya, jù li akokò ti ọkà ati ọti-waini wọn pọ̀ si. 8 Emi o dubulẹ li alafia, emi o si sùn: nitori iwọ, Oluwa, nikanṣoṣo li o mu mi joko li ailewu. ORI 5 1 (Si olori akọrin ti Nehilotu, Orin Dafidi.) Fi eti si ọ̀rọ mi, Oluwa, kiyesi iṣaro mi. 2 Fetisi ohùn igbe mi, Ọba mi, ati Ọlọrun mi: nitori iwọ li emi o gbadura si. 3 Ohùn mi ni iwọ o gbọ́ li owurọ̀, Oluwa; li owurọ̀ emi o fi adura mi si ọdọ rẹ, emi o si ma gbé oju soke. 4 Nitoripe iwọ kì iṣe Ọlọrun ti o ni inu-didùn si ìwa-buburu: bẹ̃ni ibi kì yio ba ọ gbe. 5 Awọn aṣiwere kì yio duro li oju rẹ: iwọ korira gbogbo awọn oniṣẹ ẹ̀ṣẹ. 6 Iwọ o pa awọn ti nsọ̀rọ ayalegbe run: Oluwa yio korira enia ẹ̀jẹ ati ẹlẹtan. 7 Ṣugbọn bi o ṣe ti emi ni, emi o wá sinu ile rẹ ninu ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ: ati ninu ẹ̀ru rẹ li emi o ma sìn siha tẹmpili mimọ́ rẹ. 8 Siwaju mi, Oluwa, ninu ododo re nitori awon ota mi; mu ọ̀na rẹ tọ́ niwaju mi. 9 Nitoriti kò si otitọ li ẹnu wọn; ìhà inú wọn jẹ́ ìwà búburú púpọ̀; ibojì tí ó ṣí sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi npọnni. 10 Iwọ pa wọn run, Ọlọrun; kí wọ́n ṣubú nípa ìmọ̀ràn ara wọn; lé wọn jáde nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrékọjá wọn; nitoriti nwọn ti ṣọ̀tẹ si ọ. 11 Ṣugbọn jẹ ki gbogbo awọn ti o gbẹkẹle ọ ki o yọ̀: jẹ ki nwọn ki o ma hó fun ayọ̀ lailai, nitoriti iwọ dáàbò bò wọn: jẹ ki awọn ti o fẹ orukọ rẹ pẹlu ki o yọ̀ ninu rẹ. 12 Nitoripe iwọ, Oluwa, ni yio bukún fun olododo; ore-ọfẹ ni iwọ o fi yi i ka bi asà. ORI 6 1 (Si olori akọrin lori Neginotu sori Ṣeminiti, Orin Dafidi.) OLUWA, máṣe ba mi wi ninu ibinu rẹ, má si ṣe nà mi ninu ibinu gbigbona rẹ. 2 Oluwa, ṣãnu fun mi; nitori alailagbara li emi: Oluwa, mu mi lara da; nitoriti egungun mi bajẹ. 3 Ọkàn mi bàjẹ́ pẹlu: ṣugbọn iwọ, Oluwa, yio ti pẹ to? 4 Pada, Oluwa, gba ọkàn mi là: gbà mi nitori ãnu rẹ. 5 Nitoripe kò si iranti rẹ li ikú: ninu isa-okú tani yio dupẹ fun ọ?


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook