Skip to main content

Yoruba - The Book of Prophet Zephaniah

Page 1

Sefaniah ORI 1 1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Sefaniah wá, ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hiskiah, li ọjọ́ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda. 2 Emi o run ohun gbogbo patapata kuro lori ilẹ, li Oluwa wi. 3 Emi o run enia ati ẹranko; Emi o run awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹja okun, ati ohun ikọsẹ pẹlu awọn enia buburu; emi o si ke enia kuro ni ilẹ na, li Oluwa wi. 4 Emi o si na ọwọ́ mi si Juda, ati sori gbogbo awọn olugbe Jerusalemu; emi o si ke iyokù Baali kuro nihinyi, ati orukọ Kemarimu pẹlu awọn alufa; 5 Ati awọn ti nsìn ogun ọrun lori awọn ile; ati awọn ti nsìn ati awọn ti o fi Oluwa bura, ati awọn ti o fi Malkamu bura; 6 Ati awọn ti o yipada kuro lọdọ Oluwa; ati awọn ti kò wá Oluwa, bẹ̃ni nwọn kò si bère lọwọ rẹ̀. 7 Pa ẹnu rẹ mọ́ niwaju Oluwa Ọlọrun: nitoriti ọjọ́ Oluwa kù si dẹ̀dẹ: nitoriti Oluwa ti pèse ẹbọ, o ti pè awọn alejo rẹ̀. 8 Yio si ṣe li ọjọ́ ẹbọ Oluwa, li emi o jẹ awọn ijoye, ati awọn ọmọ ọba, ati gbogbo awọn ti o wọ̀ li aṣọ àjeji. 9 Li ọjọ kanna pẹlu li emi o jẹ gbogbo awọn ti nfò ni iloro, ti o kún ile oluwa wọn pẹlu iwa-ipa ati ẹ̀tan. 10 Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa wi, ariwo ẹkún yio ti ẹnu ibode ẹja wá, ati igbe lati ihà keji wá, ati ipakà nla lati awọn òke wá. 11 Ẹ hu, ẹnyin olugbe Makteṣi, nitoriti a ti ke gbogbo awọn oniṣòwo lulẹ; gbogbo awọn ti o ru fadaka ni a ke kuro. 12. Yio si ṣe li akokò na, ti emi o fi fitila wá Jerusalemu wò, emi o si jẹ awọn ọkunrin ti o joko lori ibu wọn wò: ti nwi li ọkàn wọn pe, Oluwa kì yio ṣe rere, bẹñ i kì yio ṣe buburu. 13 Nitorina li ọrọ̀ wọn yio di ikogun, ati ile wọn yio di ahoro: nwọn o kọ́ ile pẹlu, ṣugbọn nwọn kì yio gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgbà-àjara, ṣugbọn nwọn kì yio mu ọti-waini rẹ̀. 14 Ọjọ nla Oluwa kù si dẹ̀dẹ, o kù si dẹ̀dẹ, o si yara gidigidi, ani ohùn ọjọ́ Oluwa: alagbara ọkunrin yio kigbe kikoro nibẹ̀. 15 Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìbínú,ọjọ́ ìdààmú àti ìdààmú,ọjọ́ ìsọdahoro àti ìsọdahoro,ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,ọjọ́ ìkùukùu àti òkùnkùn biribiri. 16 Ọjọ ipè ati idagiri si ilu olodi, ati si awọn ile-iṣọ giga. 17 Emi o si mu ipọnju wá sori enia, ti nwọn o ma rìn bi afọju, nitoriti nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa: a o si ta ẹ̀jẹ wọn silẹ bi ekuru, ati ẹran-ara wọn bi igbẹ́.

18 Fadaka tabi wurà wọn kì yio le gbà wọn li ọjọ ibinu Oluwa; ṣugbọn iná owú rẹ̀ li a o fi run gbogbo ilẹ na: nitoriti yio yara mu gbogbo awọn ti ngbe ilẹ na run. ORI 2 1 Ẹ kó ara nyin jọ, nitõtọ, ẹ ko ara nyin jọ, ẹnyin orilẹ-ède ti kò fẹ; 2 Ki aṣẹ na to jade, ki ọjọ na to kọja bi iyangbo, ki ibinu kikan Oluwa to de sori nyin, ki ọjọ ibinu Oluwa to de sori nyin. 3 Ẹ wá OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ayé, tí ẹ ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ẹ wá ododo, ẹ wá ìwa tutu: bọya a o fi nyin pamọ li ọjọ ibinu Oluwa. 4 Nitoripe a o kọ̀ Gasa silẹ, ati Aṣkeloni ni ahoro: nwọn o lé Aṣdodu jade li ọsán, a o si fà Ekroni tu. 5 Egbe ni fun awọn ti ngbe eti okun, orilẹ-ède awọn Kereti! ọ̀rọ̀ OLUWA lòdì sí yín; Iwọ Kenaani, ilẹ awọn Filistini, ani emi o pa ọ run, ti kì yio fi si olugbe. 6 Ati àgbegbe okun yio si jẹ ibujoko ati ile kekere fun awọn oluṣọ-agutan, ati agbo fun agbo-ẹran. 7 Ààlà náà yóò sì wà fún ìyókù ilé Júdà; nwọn o jẹun lori rẹ̀: ni ile Aṣkeloni ni nwọn o dubulẹ li aṣalẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wọn yio bẹ̀ wọn wò, yio si yi igbekun wọn pada. 8 Emi ti gbọ́ ẹ̀gan Moabu, ati ẹ̀gan awọn ọmọ Ammoni, nipa eyiti nwọn ti gàn awọn enia mi, ti nwọn si ti gbé ara wọn ga si àgbegbe wọn. 9 Nitorina bi emi ti wà, li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Nitõtọ Moabu yio dabi Sodomu, ati awọn ọmọ Ammoni yio dabi Gomorra, ati ibisi idọ̀, ati ọgbun iyọ̀, ati ahoro lailai: iyokù mi; enia yio si kó wọn, ati awọn iyokù ti awọn enia mi yio si gbà wọn. 10 Eyi ni nwọn o ni nitori igberaga wọn, nitoriti nwọn ti gàn, nwọn si ti gbé ara wọn ga si awọn enia Oluwa awọn ọmọ-ogun. 11 OLUWA yio si li ẹ̀ru fun wọn: nitoriti yio pa gbogbo oriṣa aiye li ebi; enia yio si ma sìn i, olukuluku lati ipò rẹ̀ wá, ani gbogbo erekùṣu awọn keferi. 12 Ẹnyin ará Etiopia pẹlu, a o fi idà mi pa nyin. 13 On o si nà ọwọ́ rẹ̀ si ariwa, yio si run Assiria; emi o si sọ Ninefe di ahoro, yio si gbẹ bi aginju. . ohùn wọn yoo kọrin ni awọn ferese; idahoro yio wà ni iloro: nitori on o tú iṣẹ́ kedari silẹ. 15 Eyi ni ilu ayọ̀ ti o joko li aisimi, ti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, Emi ni, kò si si ẹlomiran lẹhin mi: bawo ni o ṣe di ahoro, ibiti ẹranko dubulẹ si! olukuluku ẹniti o kọja lọdọ rẹ̀ yio pò, yio si mì ọwọ́ rẹ̀.

ORI 3


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook