Skip to main content

Yoruba - The Book of Prophet Zechariah

Page 1

Sekariah ORI 1 1 LI oṣù kẹjọ, li ọdun keji Dariusi, li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Sekariah, ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo woli wá, wipe, 2 OLUWA ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3 Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipada si mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si yipada si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 4. Ẹ máṣe dabi awọn baba nyin, ti awọn woli iṣãju kigbe si wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Ẹ yipada nisisiyi kuro ninu ọ̀na buburu nyin, ati kuro ninu iṣe buburu nyin: ṣugbọn nwọn kò gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò gbọ́ ti emi, li Oluwa wi. 5 Awọn baba nyin, nibo ni nwọn wà? ati awọn woli, nwọn ha wà lãye lailai? 6 Ṣugbọn ọ̀rọ mi ati ilana mi, ti mo palaṣẹ fun awọn iranṣẹ mi, awọn woli, nwọn kò ha dì awọn baba nyin mu? nwọn si pada nwọn si wipe, Gẹgẹ bi OLUWA awọn ọmọ-ogun ti rò lati ṣe si wa, gẹgẹ bi ọ̀na wa, ati gẹgẹ bi iṣe wa, bẹ̃li o ṣe si wa. 7 Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kọkanla, tíí ṣe oṣù Sebati, ní ọdún kejì Dáríúsì, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ wòlíì Sekaráyà ọmọ Berekáyà ọmọ Ídò wòlíì wá pé: 8 Mo si ri li oru, si kiyesi i, ọkunrin kan gun ẹṣin pupa kan, o si duro lãrin awọn igi mirtili ti o wà ni isalẹ; lẹhin rẹ̀ ni awọn ẹṣin pupa, abilà, ati funfun wà. 9 Nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini wọnyi? Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Emi o fi ohun ti awọn wọnyi iṣe hàn ọ. 10 Ọkunrin na ti o duro lãrin awọn igi mirtili na dahùn o si wipe, Wọnyi li awọn ti OLUWA rán lati ma rìn sode sodò li aiye. . 12 Angeli OLUWA na si dahùn o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, yio ti pẹ to ti iwọ kì yio ṣãnu fun Jerusalemu ati fun awọn ilu Juda, ti iwọ ti binu si li ãdọrin ọdun wọnyi? 13 OLUWA si fi ọ̀rọ rere ati ọ̀rọ itunu da angẹli na ti mba mi sọ̀rọ lohùn. 14 Angeli ti mba mi sọ̀rọ si wi fun mi pe, Iwọ kigbe, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Mo jowú fun Jerusalemu ati fun Sioni pẹlu owú nla. . 16 Nitorina bayi li Oluwa wi; Emi pada si Jerusalemu pẹlu ãnu: a o kọ́ ile mi sinu rẹ̀, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, a o si ta okùn kan sori Jerusalemu. 17 Kigbe sibẹ, wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Awọn ilu mi nipa alafia yoo tun tan kaakiri; Oluwa yio si tun tu Sioni ninu, yio si tun yan Jerusalemu. 18 Nigbana ni mo gbe oju mi soke, mo si ri, si kiyesi i, iwo mẹrin. 19 Mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ pe, Kini wọnyi? O si da mi lohùn pe, Wọnyi li awọn iwo ti o ti tú Juda, Israeli, ati Jerusalemu ká. 20 OLUWA si fi awọn gbẹnagbẹna mẹrin hàn mi. 21 Nigbana ni mo wipe, Kili awọn wọnyi wá lati ṣe? O si wipe, Wọnyi ni iwo ti o ti tú Juda ka, tobẹ̃ ti ẹnikan kò gbe ori rẹ̀ soke: ṣugbọn awọn wọnyi wá lati dẹ́rùba wọn, lati lé iwo awọn Keferi jade, ti o gbé iwo wọn soke sori ilẹ Juda lati tú u ká.

ORI 2 1 MO si tun gbe oju mi soke, mo si wò, si kiyesi i, ọkunrin kan ti o ti okùn ìwọn li ọwọ́ rẹ̀. 2 Nigbana ni mo wipe, Nibo ni iwọ nlọ? O si wi fun mi pe, Lati wọ̀n Jerusalemu, lati wò bawo ni ibú rẹ̀, ati bawo ni gigùn rẹ̀ ṣe. 3 Si kiyesi i, angẹli ti mba mi sọ̀rọ jade lọ, angẹli miran si jade lọ ipade rẹ̀; 4 O si wi fun u pe, Sá, sọ fun ọdọmọkunrin yi pe, Jerusalemu li a o ma gbe bi ilu ti kò ni odi nitori ọ̀pọlọpọ enia ati ẹran-ọ̀sin ninu rẹ̀. 5 Nitoripe emi, li Oluwa wi, emi o jẹ odi iná fun u yika, emi o si jẹ ogo lãrin rẹ̀. 6 Ho, ho, jade wá, ki o si sá kuro ni ilẹ ariwa, li Oluwa wi: nitori emi ti nà nyin kakiri bi afẹfẹ mẹrin ọrun, li Oluwa wi. 7 Gbà ara rẹ lọ́wọ́, ìwọ Sioni, tí o ń gbé pẹlu ọmọbinrin Babiloni. 8 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Lẹ́yìn ògo, ó rán mi sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n kó yín ní ìjẹ: nítorí ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín, ó fọwọ́ kan pópó ojú rẹ̀. 9 Nitori kiyesi i, emi o mì ọwọ́ mi le wọn, nwọn o si di ikogun fun awọn iranṣẹ wọn: ẹnyin o si mọ̀ pe Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi. 10 Kọrin, si yọ̀, iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori, wò o, emi mbọ̀, emi o si ma gbe ãrin rẹ, li Oluwa wi. 11 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède ni yio si dapọ mọ Oluwa li ọjọ na, nwọn o si jẹ enia mi: emi o si ma gbe ãrin rẹ, iwọ o si mọ̀ pe Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si ọ. 12 Oluwa yio si jogun Juda ipín rẹ̀ ni ilẹ mimọ́, yio si tun yan Jerusalemu. 13 Ẹ dákẹ́, gbogbo eniyan, níwájú OLUWA,nítorí ó ti jí dìde kúrò ní ibùgbé mímọ́ rẹ̀. ORI 3 1 O si fi Joṣua olori alufa hàn mi, o duro niwaju angẹli Oluwa, Satani si duro li ọwọ́ ọtún rẹ̀ lati koju rẹ̀. 2 OLUWA si wi fun Satani pe, Oluwa ba ọ wi, iwọ Satani; ani Oluwa ti o ti yàn Jerusalemu, ba ọ wi: eyi ha ha ha fà yọ kuro ninu iná? 3 A si wọ̀ Joṣua li aṣọ ẽri, o si duro niwaju angẹli na. 4 O si dahùn o si sọ fun awọn ti o duro niwaju rẹ̀ pe, Ẹ bọ́ aṣọ ẽri nì kuro lara rẹ̀. On si wipe, Kiyesi i, emi ti mu ẹ̀ṣẹ rẹ kọja lọdọ rẹ, emi o si fi àparọ aṣọ wọ̀ ọ. 5 Emi si wipe, Ki nwọn ki o fi fila daradara kan le e li ori. Bẹ̃ni nwọn fi fila didan lé e li ori, nwọn si fi aṣọ wọ̀ ọ. Angeli OLUWA na si duro tì i. 6 Angeli OLUWA na si sọ fun Joṣua pe, 7 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Bi iwọ o ba rìn li ọ̀na mi, ati bi iwọ o ba pa aṣẹ mi mọ́, nigbana ni iwọ o ṣe idajọ ile mi pẹlu, iwọ o si pa àgbala mi mọ́ pẹlu, emi o si fun ọ li àye lati ma rìn lãrin awọn ti o duro nibẹ̀. 8 Gbọ́ nisisiyi, iwọ Joṣua olori alufa, iwọ, ati awọn ẹgbẹ rẹ ti o joko niwaju rẹ: nitoriti ẹnu yà wọn li enia: sa wò o, emi o mu iranṣẹ mi jade, Ẹ̀ka. 9 Nitori kiyesi i, okuta ti mo ti gbe kalẹ niwaju Joṣua; sori okuta kan li oju meje yio wà: kiyesi i, emi o fin finfin rẹ̀, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, emi o si mu ẹ̀ṣẹ ilẹ na kuro ni ijọ kan. 10 Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, olukuluku nyin o pè aladugbo rẹ̀ labẹ ajara ati labẹ igi ọpọtọ.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of Prophet Zechariah by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu