Skip to main content

Yoruba - The Book of Prophet Micah

Page 1

Mika ORI 1 1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Mika ará Morati wá li ọjọ́ Jotamu, Ahasi, ati Hesekiah, awọn ọba Juda, ti o ri niti Samaria ati Jerusalemu. 2 Ẹ gbọ́, gbogbo ẹnyin enia; fetisilẹ, iwọ aiye, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: si jẹ ki Oluwa Ọlọrun ki o ṣe ẹlẹri si ọ, Oluwa lati tẹmpili mimọ́ rẹ̀ wá. 3 Nitori kiyesi i, Oluwa jade kuro ni ipò rẹ̀, yio si sọ̀kalẹ, yio si tẹ̀ ibi giga aiye mọlẹ. 4 Awọn oke-nla yio si di didà labẹ rẹ̀, ati awọn afonifoji li ao là, bi ida niwaju iná, ati bi omi ti a dà silẹ ni ibi giga. 5 Nitori irekọja Jakobu ni gbogbo eyi, ati nitori ẹ̀ṣẹ ile Israeli. Kí ni ìrékọjá Jakọbu? Ṣebí Samáríà ni? ati kini awọn ibi giga Juda? Ṣebí Jerusalemu ni? 6 Nitorina emi o ṣe Samaria bi òkiti oko, ati bi gbigbin ọgba-àjara: emi o si dà okuta rẹ̀ lulẹ sinu afonifoji, emi o si fi ipilẹ rẹ̀ hàn. 7 Ati gbogbo ere fifin rẹ̀ li a o lù tũtu, ati gbogbo ọ̀ya rẹ̀ li a o fi iná sun, ati gbogbo ere rẹ̀ li emi o sọ di ahoro: nitoriti o gbà a lati owo ọya aṣẹwó, nwọn o si pada si ọ̀ya aṣẹwó. 8 Nítorí náà èmi yóò pohùnréré ẹkún, èmi yóò sì pohùnréré ẹkún,Èmi yóò lọ ní ìhòòhò àti ní ìhòòhò:Èmi yóò sì pohùnréré ẹkún bí àwọn ọ̀rá,àti ọ̀fọ̀ bí ògòǹgò. 9 Nitoripe ọgbẹ rẹ̀ kò le wosan; nitoriti o de Juda; o ti de ẹnu-bode awọn enia mi, ani si Jerusalemu. 10. Ẹ máṣe sọ ọ ni Gati, ẹ má si sọkun rara: ni ile Afra yi ara rẹ ka ninu erupẹ. 11 Ẹ lọ, ẹ̀yin ará Safiri,ní ìhòòhò ìtìjú yín. yio gba iduro rẹ̀ lọwọ rẹ. 12 Nitoriti awọn ara Marotu nduro de ire: ṣugbọn ibi sọkalẹ lati ọdọ Oluwa wá si ẹnu-bode Jerusalemu. 13 Iwọ olugbe Lakiṣi, di kẹkẹ́ mọ́ ẹranko ti o yara: on ni ipilẹṣẹ ẹ̀ṣẹ fun ọmọbinrin Sioni: nitoriti a ri irekọja Israeli ninu rẹ. 14 Nitorina ni iwọ o fi ẹ̀bun fun Moreṣeti-gati: awọn ile Aksibu yio jẹ eke fun awọn ọba Israeli. 15 Ṣugbọn emi o mu arole kan tọ̀ ọ wá, iwọ olugbe Mareṣa: on o wá si Adullamu ogo Israeli. 16 Pa ara rẹ pá, ki o si rẹ́ ara rẹ kuro nitori awọn ọmọ ẹlẹgẹ rẹ; mú ìpárí rẹ di púpọ̀ bí idì; nitoriti nwọn lọ si igbekun lọdọ rẹ. ORI 2 1 EGBE ni fun awọn ti ngbiro ẹ̀ṣẹ, ti nwọn si nṣe buburu lori akete wọn! nigbati ilẹ ba mọ́, nwọn a ṣe e, nitoriti o wà li agbara ọwọ́ wọn. 2 Nwọn si ṣojukokoro oko, nwọn si fi agbara gbà wọn; ati ile, nwọn si kó wọn lọ: bẹ̃ni nwọn ni enia loju, ati ile rẹ̀, ani enia ati iní rẹ̀. 3 Nitorina bayi li Oluwa wi; Kiyesi i, si idile yi li emi pète ibi kan, ninu eyiti ẹnyin ki yio ṣi ọrùn nyin kuro; bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ lọ pẹlu igberaga: nitori akoko yi buburu. 4 Li ọjọ na li ẹnikan yio pa owe si nyin, nwọn o si pohùnrére ẹkun kikan, nwọn o si wipe, A ti pa wa run patapata: o ti yi ipín awọn enia mi pada: bawo ni o ti mu u kuro lọdọ mi! li o yipada li o ti pín oko wa.

5 Nitorina iwọ ki yio ni ẹnikan ti yio sọ okùn nipa keké ninu ijọ OLUWA. 6 Ẹ má sọtẹlẹ, ni nwọn wi fun awọn ti nsọtẹlẹ: nwọn kì yio sọtẹlẹ fun wọn, ki oju ki o má ba tì wọn. 7 Iwọ ti a npè ni ile Jakobu, ẹmi Oluwa ha le bi? iṣe rẹ̀ ni wọnyi? ọ̀rọ mi kò ha ṣe rere fun ẹniti nrin dede bi? 8 Ani li òpin awọn enia mi ti dide bi ọta: ẹnyin fà aṣọawọ̀n-aṣọ kuro li ọwọ́ awọn ti nkọja li ailewu, bi enia ti o korira ogun. 9 Awọn obinrin enia mi li ẹnyin ti lé jade kuro ni ile daradara wọn; li ọwọ awọn ọmọ wọn li ẹnyin ti gbà ogo mi lailai. 10 Ẹ dide, ki ẹ si lọ; nitori eyi kì iṣe isimi nyin: nitoriti o di aimọ́, yio si pa nyin run, ani pẹlu iparun kikan. 11 Bi ọkunrin kan ti nrin ninu ẹmi ati eke ba ṣeke, wipe, Emi o sọtẹlẹ fun ọ ti ọti-waini ati ọti lile; on ni yio si ṣe woli awọn enia yi. 12 Nitõtọ emi o pejọ, Jakobu, gbogbo rẹ; Dájúdájú, èmi yóò kó àwọn ìyókù Ísírẹ́lì jọ; Emi o ko wọn jọ bi agutan Bosra, bi agbo-ẹran lãrin agbo wọn: nwọn o hó nla nitori ọ̀pọlọpọ enia. 13 Ẹniti o fọ́ gòke wá siwaju wọn: nwọn ti ya, nwọn si là ẹnu-bode kọja, nwọn si jade lọdọ rẹ̀: ọba wọn yio si kọja niwaju wọn, Oluwa yio si wà li ori wọn. ORI 3 1 MO si wipe, Gbọ́, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori Jakobu, ati ẹnyin olori ile Israeli; Kì ha ṣe fun ọ lati mọ idajọ? 2 Ti o korira rere, ti nwọn si fẹ buburu; tí wọ́n já awọ wọn kúrò lára wọn, ati ẹran ara wọn kúrò ní egungun wọn; 3 Ti njẹ ẹran-ara awọn enia mi pẹlu, ti nwọn si já awọ wọn kuro lara wọn; nwọn si fọ́ egungun wọn, nwọn si gé wọn tũtu, bi ti ìkòkò, ati bi ẹran ninu agbada. 4 Nigbana ni nwọn o kigbe pè Oluwa, ṣugbọn on kì yio gbọ́ ti wọn: yio tilẹ pa oju rẹ̀ mọ́ kuro lara wọn li akoko na, gẹgẹ bi nwọn ti huwa buburu niti iṣe wọn. 5 Bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nmu awọn enia mi ṣìna, ti nwọn fi ehin wọn bu, ti nwọn si nkigbe pe, Alafia; ati ẹniti kò fi si ẹnu wọn, ani nwọn mura ogun si i. 6 Nitorina oru yio jasi fun nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; okunkun yio si ṣokunkun fun nyin, ti ẹnyin ki yio fi ṣe àfọ̀ṣẹ; òòrùn yóò sì wọ̀ lórí àwọn wòlíì, ọjọ́ náà yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn. . nitori ko si idahun ti Olorun. 8 Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa Ẹmí Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu rẹ̀ fun, ati fun Israeli ẹ̀ṣẹ rẹ̀. 9. Emi bẹ̀ nyin, ẹ gbọ́ eyi, ẹnyin olori ile Jakobu, ati awọn ijoye ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si nyi gbogbo otitọ li aida. 10 Nwọn fi ẹ̀jẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu ẹ̀ṣẹ. 11. Awọn olori wọn nṣe idajọ fun ère, awọn alufa rẹ̀ si ma kọ́ni fun ọ̀ya, ati awọn woli rẹ̀ a nsọ̀rọ fun owo: sibẹ nwọn o gbẹkẹle Oluwa, nwọn o si wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? buburu ko le wa sori wa. 12 Nitorina li a o ṣe tulẹ̀ Sioni nitori nyin bi oko, Jerusalemu yio si di òkiti, ati òke nla ile bi ibi giga igbo.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of Prophet Micah by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu