Skip to main content

Yoruba - The Book of Prophet Malachi

Page 1

Malaki ORI 1 1 Ọ̀ RỌ Ọ̀RỌ Oluwa si Israeli nipa ọwọ Malaki. 2 Emi ti fẹ nyin, li Oluwa wi. Sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Níbo ni o fẹ́ràn wa? Esau ko ha ṣe arakunrin Jakọbu bi? li Oluwa wi: ṣugbọn emi fẹ Jakobu. 3 Emi si korira Esau, mo si sọ awọn oke-nla rẹ̀ ati ilẹ-iní rẹ̀ di ahoro fun awọn ẹranko ijù. 4. Bi Edomu si wipe, Awa di talakà, ṣugbọn awa o pada, a o si kọ́ ibi ahoro; bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Nwọn o kọ́, ṣugbọn emi o wó lulẹ; nwọn o si ma pè wọn ni àla ìwa-buburu, ati awọn enia ti Oluwa binu si lailai. 5 Oju nyin yio si ri, ẹnyin o si wipe, A o gbé Oluwa ga lati àgbegbe Israeli wá. 6 Ọmọ a ma bu ọla fun baba rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ fun oluwa rẹ̀: njẹ bi emi ba ṣe baba, ọlá mi da? bi emi ba si ṣe olori, nibo ni ẹ̀ru mi wà? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi fun nyin, ẹnyin alufa, ti o gàn orukọ mi. Ẹ̀yin sì wí pé, “Níbo ni àwa fi kẹ́gàn orúkọ rẹ? 7 Ẹnyin fi àkara aimọ́ rubọ lori pẹpẹ mi; ẹnyin si wipe, Kili awa fi sọ ọ di aimọ́? Ninu eyi li ẹnyin wipe, Tabili Oluwa jẹ ẹgan. 8 Bi ẹnyin ba si fi afọju rubọ, kò ha ṣe buburu? bí ẹ bá sì fi arọ àti aláìsàn rúbọ, kò ha burú? fi fun bãlẹ rẹ nisisiyi; inu rẹ̀ yio ha dùn si ọ, tabi ki o ṣe ojuṣaju rẹ? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 9 Njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ nyin, ẹ bẹ Ọlọrun ki o le ṣe ore-ọfẹ fun wa: nipa ọwọ nyin li eyi ti ri: on o ha kà nyin si bi? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 10 Tani ninu nyin ti o le ti ilẹkun lasan? bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe da iná lori pẹpẹ mi li asan. Emi ko ni inu-didun si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, bẹ̃li emi kì yio gba ọrẹ lọwọ nyin. 11 Nitori lati ila-õrun titi o fi de iwọ̀ rẹ̀, orukọ mi yio tobi lãrin awọn Keferi; ati ni ibi gbogbo li a o fi turari si orukọ mi, ati ẹbọ mimọ́: nitori orukọ mi yio tobi lãrin awọn keferi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 12 Ṣugbọn ẹnyin ti bà a jẹ́, niti ẹnyin wipe, Tabili OLUWA di aimọ́; ati eso rẹ̀, ani onjẹ rẹ̀, jẹ ẹgan. 13 Ẹnyin si wipe, Kiyesi i, ãrẹ kili o! ẹnyin si ti run si i, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; ẹnyin si mu eyi ti o fàya wá, ati arọ, ati awọn ti o ṣaisan; bayi li ẹnyin mu ọrẹ wá: emi o ha gbà eyi lọwọ nyin bi? li Oluwa wi. 14 Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà,tí ó ní akọ nínú agbo ẹran rẹ̀,tí ó sì jẹ́jẹ̀ẹ,́ tí ó sì rúbọ sí Olúwa ohun ìbàjẹ́:nítorí èmi jẹ́ ọba ńlá,ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè. ORI 2 1 ÀTI nísisìyí, ẹ̀yin àlùfáà, òfin yìí wà fún yín. " . ẹnikan yio si mu nyin lọ pẹlu rẹ̀. 4 Ẹnyin o si mọ̀ pe emi li o rán ofin yi si nyin, ki majẹmu mi ki o le wà pẹlu Lefi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 5 Majẹmu mi si wà pẹlu rẹ̀ ti ìye ati alafia; mo sì fi wọ́n fún un nítorí ẹ̀rù tí ó fi bẹ̀rù mi, ẹ̀rù sì bà á níwájú orúkọ mi. 6 Ofin otitọ mbẹ li ẹnu rẹ̀, a kò si ri ẹ̀ṣẹ li ète rẹ̀: o ba mi rìn li alafia ati ododo, o si yi ọ̀pọlọpọ pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ.

7 Nitoripe ète alufa ni ki o pa ìmọ mọ́, ki nwọn ki o si ma wá ofin li ẹnu rẹ̀: nitori onṣẹ Oluwa awọn ọmọ-ogun ni iṣe. 8 Ṣugbọn ẹnyin ti yà kuro li ọ̀na; ẹnyin ti mu ọpọlọpọ kọsẹ si ofin; ẹnyin ti ba majẹmu Lefi jẹ, li Oluwa awọn ọmọogun wi. 9 Nítorí náà, èmi náà ti sọ yín di ẹni ẹ̀gàn àti ẹni ẹ̀gàn níwájú gbogbo ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin kò ti pa ọ̀nà mi mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe ojúsàájú nínú òfin. 10 Be e ma yin otọ́ dopo wẹ mímẹpo wẹ yin ya? Ọlọrun kan kò ha da wa bi? ẽṣe ti awa fi nhùwa arekereke olukuluku si arakunrin rẹ̀, nipa sisọ majẹmu awọn baba wa di alaimọ́? 11 Juda ti huwa arekereke, a si ti ṣe ohun irira ni Israeli ati ni Jerusalemu; nitori Juda ti sọ ìwa-mimọ́ Oluwa di aimọ́, ti o fẹ́, o si ti fẹ́ ọmọbinrin ọlọrun ajeji kan ni iyawo. 12 Oluwa yio ke ọkunrin na ti o ṣe eyi kuro, olori ati amoye kuro ninu agọ Jakobu, ati ẹniti o ru ọrẹ-ẹbọ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun. 13 Eyi li ẹnyin si tun ṣe, ti ẹ fi omije bò pẹpẹ Oluwa, pẹlu ẹkún, ati pẹlu igbe, tobẹ̃ ti on kò fi kà ẹbọ na si mọ́, tabi ki o fi inu rere gbà a lọwọ nyin. 14 Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ẽṣe? Nitoriti OLUWA ti ṣe ẹlẹri lãrin iwọ ati aya ewe rẹ, si ẹniti iwọ ti hùwa arekerekè si: ṣugbọn on li ẹlẹgbẹ rẹ, ati aya majẹmu rẹ. 15 On kò ha si ṣe ọkan bi? Síbẹ̀ ó ní ìyókù ẹ̀mí. Ati idi ti ọkan? Kí ó lè wá irúgbìn oníwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹnikẹ́ni má sì ṣe àdàkàdekè sí aya ìgbà èwe rẹ̀. 16 Nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, wipe, on korira ikọsilẹ: nitori ẹnikan fi ìwa-ipa bò aṣọ rẹ̀, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitorina ẹ ṣọ́ ẹmi nyin, ki ẹ má ba ṣe arekereke. 17 Ẹnyin ti fi ọ̀rọ nyin da OLUWA li agara. Sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, “Níbo ni a ti dá a lágara? Nigbati ẹnyin wipe, Olukuluku ẹniti o nṣe buburu, o dara li oju Oluwa, inu rẹ̀ si dùn si wọn; tabi, Nibo li Ọlọrun idajọ wà? ORI 3 1 Kiyesi i, Emi o rán onṣẹ mi, on o si tun ọ̀na ṣe niwaju mi: Oluwa, ti ẹnyin nwá, yio si wá si tempili rẹ̀ lojiji, ani onṣẹ majẹmu, ẹniti inu nyin dùn si: wò o, on mbọ̀, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 2 Ṣugbọn tali o le duro li ọjọ wiwa rẹ̀? ati tani yio duro nigbati o ba farahan? nítorí ó dàbí iná olùyọ́mọ́, àti bí ọṣẹ apẹ̀rẹ̀. 3 Yóò sì jókòó bí ẹni tí ń yọ́ fàdákà tí ó sì ń wẹ̀: yóò sì wẹ àwọn ọmọ Léfì mọ́, yóò sì wẹ̀ wọ́n mọ́ gẹ́gẹ́ bí wúrà àti fàdákà, kí wọn lè mú ọrẹ wá fún Olúwa ní òdodo. 4 Nigbana li ọrẹ-ẹbọ Juda ati Jerusalemu yio dùn si Oluwa, gẹgẹ bi ti igbãni, ati bi ti atijọ. 5 Emi o si sunmọ ọ fun idajọ; Emi o si jẹ ẹlẹri kánkán si awọn oṣó, ati si awọn panṣaga, ati si awọn olufira eke, ati si awọn ti nṣe alagbaṣe li ọ̀ya rẹ̀ lara, awọn opó, ati alainibaba, ati awọn ti o yi alejò kuro ninu ẹtọ rẹ̀, ti nwọn kò si bẹ̀ru mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. 6 Nitori emi li OLUWA, emi kò yipada; nítorí náà ẹ̀yin ọmọ Jakọbu kò lè parun. 7 Ani lati ọjọ́ awọn baba nyin li ẹnyin ti yapa kuro ninu ofin mi, ẹnyin kò si pa wọn mọ́. Pada si mi, emi o si yipada si nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kini awa o pada? 8 Ènìyàn yóò ha ja Ọlọ́run lólè bí? Síbẹ̀ ẹ̀yin ti jà mí lólè. Ṣugbọn ẹnyin wipe, Ninu kili awa fi ja ọ? Ninu idamẹwa ati awọn ọrẹ.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook