Awọn nọmba ORI 1 1 OLUWA si sọ fun Mose ni ijù Sinai, ninu agọ́ ajọ, li ọjọ́ kini oṣù keji, li ọdun keji lẹhin ti nwọn ti ilẹ Egipti jade wá, wipe, 2. Ẹ ka iye gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi idile wọn, nipa ile baba wọn, pẹlu iye orukọ wọn, olukuluku ọkunrin gẹgẹ bi ori wọn; 3 Lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli: iwọ ati Aaroni ni ki o kaye wọn gẹgẹ bi ogun wọn. 4 Ati pẹlu nyin ki ọkunrin kan ki o wà ninu olukuluku ẹ̀ya; olukuluku olori ile awọn baba rẹ̀. 5 Wọnyi si li orukọ awọn ọkunrin na ti yio duro pẹlu nyin: ti ẹ̀ya Reubeni; Elisuri ọmọ Ṣedeuri. 6 Ti Simeoni; Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai. 7 Ti Juda; Naṣoni ọmọ Aminadabu. 8 Ti Issakari; Netaneli ọmọ Suari. 9 Ti Sebuluni; Eliabu ọmọ Heloni. 10 Ninu awọn ọmọ Josefu: ti Efraimu; Eliṣama ọmọ Amihudu: ti Manasse; Gamalieli ọmọ Pedahsuri. 11 Ti Benjamini; Abidani ọmọ Gideoni. 12 Ti Dani; Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai. 13 Ti Aṣeri; Pagieli ọmọ Okrani. 14 Ti Gadi; Eliasafu ọmọ Deueli. 15 Ti Naftali; Ahira ọmọ Enani. 16 Wọnyi li okiki ijọ enia, olori ẹ̀ya awọn baba wọn, olori ẹgbẹgbẹrun ni Israeli. 17 Mose ati Aaroni si mú awọn ọkunrin wọnyi ti a fi orukọ wọn hàn: 18 Nwọn si pè gbogbo ijọ enia jọ li ọjọ́ kini oṣù keji, nwọn si sọ idile wọn nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, nipa ibobo wọn. 19 Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni ó kà wọ́n ní ihà Sínáì. 20 Ati awọn ọmọ Reubeni, akọbi Israeli, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 21 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Reubeni, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ẹdẹgbẹta. 22 Ti awọn ọmọ Simeoni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, awọn ti a kà ninu wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, nipa ori wọn, gbogbo ọkunrin lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 23 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Simeoni, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin. 24 Ti awọn ọmọ Gadi, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 25 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Gadi, o jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ. 26 Ti awọn ọmọ Juda, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 27 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Juda, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹgbẹta.
28 Ti awọn ọmọ Issakari, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 29 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Issakari, jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le irinwo. 30 Ti awọn ọmọ Sebuluni, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 31 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le irinwo. 32 Ti awọn ọmọ Josefu, ani, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 33 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 34 Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 35 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, jẹ́ ẹgba mejilelọgbọ̀n o le igba. 36 Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 37 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le egbeje. 38 Ti awọn ọmọ Dani, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 39 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, jẹ́ ẹgba mọkanla o le ẹdẹgbẹrin. 40 Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 41 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta. 42 Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun; 43 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le egbeje. 44 Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀. 45 Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli; 46 Ani gbogbo awọn ti a kà jẹ́ ẹgbaa mẹtala o le ẹdẹgbẹta ãdọta. 47 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba wọn li a kò ka mọ́ wọn. 48 Nitoriti OLUWA ti sọ fun Mose pe, 49 Kìki ẹ̀ya Lefi ni ki iwọ ki o máṣe kà, bẹ̃ni ki iwọ ki o má si ṣe kà iye wọn mọ́ awọn ọmọ Israeli. 50 Ṣugbọn ki iwọ ki o yàn awọn ọmọ Lefi sori agọ́ ẹrí, ati sori gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati sori ohun gbogbo ti iṣe tirẹ̀: nwọn o ma rù agọ́ na, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀; nwọn o si ṣe iranṣẹ fun u, nwọn o si dó yi agọ́ na ká. 51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, awọn ọmọ Lefi ni ki o wó u palẹ: nigbati nwọn o si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e ró: alejò ti o ba si sunmọtosi ni ki a pa a. 52 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku li ibudó rẹ̀, ati olukuluku li ọpagun tirẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn.