Lefitiku ORI 1 1 OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wá pe, . 3 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti agbo-ẹran, jẹ ki o mú akọ alailabùku wá: ki o si mú u tinutinu rẹ̀ wá li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ niwaju OLUWA. 4 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si jẹ itẹwọgbà fun u lati ṣe etutu fun u. 5 Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si wọ́n ẹ̀jẹ na yika pẹpẹ ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ. 6 Ki o si já ẹbọ sisun na, ki o si gé e si ewà rẹ̀. 7 Ki awọn ọmọ Aaroni alufa ki o si fi iná sori pẹpẹ na, ki nwọn ki o si to igi na sori iná na. 8 Ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si to apakan wọn, ori, ati ọrá wọnni sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ: 9 Ṣugbọn ifun rẹ̀ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ki o wẹ̀ ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ fun ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 10 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ti agbo-ẹran, ani ti agutan, tabi ti ewurẹ fun ẹbọ sisun; kí ó mú ækùnrin tí kò ní àbààwọ́n wá. 11 Ki o si pa a ni ìha pẹpẹ ni ìha ariwa niwaju OLUWA: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wọ́n ẹ̀jẹ rẹ̀ sori pẹpẹ yiká. 12 Ki o si gé e si wẹ́wẹ, pẹlu ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: ki alufa ki o si to wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ. 13 Ṣugbọn ki o fi omi fọ ifun ati itan rẹ̀: ki alufa ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 14 Ati bi o ba ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun fun ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ti àdaba, tabi ti ẹiyẹle wá. 15 Ki alufa ki o si mú u wá si ibi pẹpẹ, ki o si gé ori rẹ̀, ki o si sun u lori pẹpẹ; ati ẹ̀jẹ rẹ̀ li a o si dà si ìha pẹpẹ; 16 Ki o si já eso rẹ̀ pẹlu iyẹ́ rẹ̀, ki o si dà a si ẹba pẹpẹ ni ìha ìla-õrùn, ni ibi ẽru. 17 Ki o si là a pẹlu iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki o máṣe yà a niya: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ, lori igi ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. ORI 2 1 NIGBATI ẹnikan ba si ru ẹbọ ohunjijẹ si OLUWA, ọrẹẹbọ rẹ̀ ki o jẹ́ ti iyẹfun daradara; yóò da òróró lé e lórí, yóò sì fi tùràrí lé e. 2 Ki o si mú u tọ̀ awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa wá: ki o si mú ikunwọ́ rẹ̀ ninu iyẹfun rẹ̀, ati ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki alufa ki o si sun ohun iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, fun ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA. 3 Ati iyokù ẹbọ ohunjijẹ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni ti ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe. 4 Ati bi iwọ ba mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si. 5 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu awopẹtẹ, ki o jẹ́ iyẹfun daradara alaiwu, ti a fi oróro pò. 6 Ki iwọ ki o yà a si wẹ́wẹ, ki o si da oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.
7 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ ti a yan ninu àwo, iyẹfun daradara ni ki a fi ṣe e pẹlu oróro. 8 Ki iwọ ki o si mú ẹbọ ohunjijẹ ti a fi nkan wọnyi ṣe wá fun OLUWA: nigbati a ba si mú u wá fun alufa, ki o mú u wá si ibi pẹpẹ. 9 Ki alufa ki o si mú ninu ẹbọ ohunjijẹ na fun iranti, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA. 10 Ati eyiti o kù ninu ẹbọ ohunjijẹ na ki o jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni ti ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe. 11 Ẹbọ ohunjijẹ kan, ti ẹnyin o mú fun OLUWA, li a kò gbọdọ fi iwukara ṣe: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi oyin kan, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe. 12 Niti ọrẹ-ẹbọ akọso, ki ẹnyin ki o mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a kò gbọdọ sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn. 13 Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o ṣe alaini ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ rúbọ. 14 Ati bi iwọ ba mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá si OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà tutù ti a fi iná jó, fun ẹbọ ohunjijẹ akọso rẹ. 15 Iwọ o si fi oróro sori rẹ̀, iwọ o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni. 16 Ki alufa ki o si sun ohun iranti rẹ̀, apakan ọkà rẹ̀ lilù, ati apakan oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA. ORI 3 1 BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u ninu agboẹran; ìbáà ṣe akọ tàbí abo, kí ó mú u rúbọ láìlábàwọ́n níwájú Olúwa. 2 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa ki o si wọ́n ẹ̀jẹ na sori pẹpẹ yiká. 3 Ki o si ru ninu ẹbọ alafia na, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun. 4 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro. 5 Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti mbẹ lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA. 6 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agboẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku. 7 Bi o ba si mú ọdọ-agutan kan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA. 8 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si wọ́n ẹ̀jẹ rẹ̀ sori pẹpẹ yiká. 9 Ki o si ru ninu ẹbọ alafia na, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀, on ni ki o mú kuro li egungun ẹhin; ati ọrá ti o bo ifun, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun. 10 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro. 11 Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni. 12 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA. 13 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si wọ́n ẹ̀jẹ rẹ̀ sori pẹpẹ yiká. 14 Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọ̀rá tí ó bo ìfun, ati gbogbo ọ̀rá tí ó bo ìfun.