Àròyé ORI 1 1 BAWO ni ilu na ṣe joko ni idahoro, ti o kún fun enia! báwo ni ó ṣe dàbí opó! ẹniti o tobi lãrin awọn orilẹ-ède, ati ọmọ-alade lãrin awọn ìgberiko, bawo ni o ṣe di ẹrú! 2 O nsọkun kikan li oru, omije rẹ̀ si mbẹ li ẹ̀rẹkẹ rẹ̀: ninu gbogbo awọn olufẹ rẹ̀, kò ni ẹnikan lati tù u ninu: gbogbo awọn ọrẹ́ rẹ̀ ti hùwa ẹ̀tan si i, nwọn di ọta rẹ̀. 3 Juda ti lọ sí ìgbèkùn nítorí ìpọ́njú,àti nítorí ìsinrú ńlá:ó ń gbé ààrin àwọn orílẹ̀-èdè,kò sì rí ìsinmi,gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni rẹ̀ sì bá a. 4 Àwọn ọ̀nà Síónì ń ṣọ̀fọ̀,nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wá síbi àjọ̀dún:gbogbo ibodè rẹ̀ ti di ahoro:àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,àwọn wúńdíá rẹ̀ ń pọ́n lójú,ó sì wà nínú kíkorò. 5 Awọn ọta rẹ̀ li olori, awọn ọta rẹ̀ ṣe rere; nitori Oluwa ti pọ́n ọ loju nitori ọ̀pọlọpọ irekọja rẹ̀: awọn ọmọ rẹ̀ ti lọ si igbekun niwaju awọn ọta. 6 Ati lati ọdọ ọmọbinrin Sioni ni gbogbo ẹwà rẹ̀ ti lọ kuro: awọn ọmọ-alade rẹ̀ dabi agbọnrin ti kò ri pápa oko, nwọn si lọ li aini agbara niwaju awọn ti nlepa. 7 Jerusalemu si ranti li ọjọ ipọnju rẹ̀, ati gbogbo ohun rere rẹ̀ ti o ni li ọjọ́ atijọ, nigbati awọn enia rẹ̀ ṣubu si ọwọ ọta, ti kò si si ẹniti o ràn u lọwọ: awọn aninilara ri i, nwọn si ṣe e. ṣe ẹlẹ́yà ní ọjọ́ ìsinmi rẹ̀. 8 Jerusalemu ti ṣẹ̀ gidigidi; nitorina li o ṣe ṣipaya: gbogbo awọn ti o bu ọla fun u kẹgan rẹ̀, nitoriti nwọn ti ri ìhoho rẹ̀: nitõtọ, o kerora, o si yipada. 9 ẽri rẹ̀ mbẹ li aṣọ igunwa rẹ̀; kò rántí ìgbẹ̀yìn rẹ̀; nitorina li o ṣe sọkalẹ wá li iyanu: kò ni olutunu. Oluwa, wo ipọnju mi: nitori ọta ti gbe ara rẹ̀ ga. 10. Ọta na ti nà ọwọ́ rẹ̀ sori gbogbo ohun didara rẹ̀: nitoriti o ti ri pe awọn keferi wọ ibi mimọ́ rẹ̀ lọ, ti iwọ palaṣẹ, ki nwọn ki o máṣe wọ̀ inu ijọ enia rẹ lọ. 11 Gbogbo awọn enia rẹ̀ kẹdùn, nwọn nwá onjẹ; nwọn ti fi ohun didùn wọn fun onjẹ lati tu ọkàn lara: wò o, Oluwa, ki o si rò; nitoriti mo di ẹ̀gàn. 12 Kò ha jẹ nkan fun nyin, gbogbo ẹnyin ti nkọja? wò ó, kí o sì wò ó bí ìbànújẹ́ kan bá wà bí ìbànújẹ́ mi, tí ó ṣe sí mi, tí OLUWA fi pọ́n mi lójú ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀. 13 Lati oke li o ti rán iná sinu egungun mi, o si bori wọn: o ti nà àwọ̀n fun ẹsẹ mi, o ti yi mi pada: o ti sọ mi di ahoro, o si ti rẹ̀ mi li ọjọ gbogbo. 14 Ọwọ́ rẹ̀ li a fi dè àjaga irekọja mi: a lọ́ wọn, nwọn si goke wá li ọrùn mi: o ti mu agbara mi ṣubu, Oluwa ti fi mi le wọn lọwọ, lọwọ ẹniti emi kò le dide. 15 Oluwa ti tẹ̀ gbogbo awọn alagbara mi mọ́ li ãrin mi: o ti pè apejọ kan si mi lati tẹ̀ awọn ọdọmọkunrin mi mọlẹ: Oluwa ti tẹ wundia, ọmọbinrin Juda, gẹgẹ bi ibi ifunti. 16 Nitori nkan wọnyi ni mo nsọkun; oju mi, oju mi nṣàn fun omi, nitori olutunu ti yio ran ọkàn mi lọwọ jina si mi: awọn ọmọ mi di ahoro, nitoriti ọta bori. 17 Sioni si nà ọwọ́ rẹ̀ jade, kò si si ẹnikan lati tù u ninu: OLUWA ti paṣẹ fun Jakobu pe, ki awọn ọta rẹ̀ ki o wà ni ayika rẹ̀: Jerusalemu jẹ obinrin ti o ni ipọnju lãrin wọn. 18 Olododo li Oluwa; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ si aṣẹ rẹ̀: ẹ gbọ́, emi bẹ̀ nyin, gbogbo enia, ki ẹ si wò ibinujẹ mi: awọn wundia mi ati awọn ọdọmọkunrin mi ti lọ si igbekun.
19 Emi pè awọn olufẹ mi, ṣugbọn nwọn tàn mi jẹ: awọn alufa mi ati awọn àgba mi jọwọ ẹmi wọn lọwọ ni ilu, nigbati nwọn nwá onjẹ wọn lati tu ọkàn wọn balẹ. 20 Wò o, Oluwa; nitoriti emi wà ninu ipọnju: ifun mi bajẹ; ọkàn mi yipada ninu mi; nitoriti emi ti ṣọ̀tẹ gidigidi: lode idà pamọ, ni ile bi ikú mbẹ. 21 Nwọn ti gbọ́ pe emi nsọ̀dùn: kò si ẹniti yio tù mi ninu: gbogbo awọn ọta mi ti gbọ́ ipọnju mi; inu wọn dùn nitoriti iwọ ṣe e: iwọ o mu ọjọ́ na ti iwọ ti pè wá, nwọn o si dabi emi. 22 Jẹ ki gbogbo ìwa-buburu wọn wá siwaju rẹ; ki o si ṣe si wọn, gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si mi nitori gbogbo irekọja mi: nitori ikẹdùn mi pọ̀, ọkàn mi si rẹ̀wẹsi. ORI 2 1 Báwo ni Olúwa ti fi ìkùukùu bo ọmọbìnrin Síónì nínú ìbínú rẹ̀,tí ó sì sọ ẹwà Ísírẹ́lì kalẹ̀ láti ọ̀run wá sí ayé,tí kò sì rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀! 2 Oluwa ti gbe gbogbo ibugbe Jakobu mì, kò si ṣãnu; o ti mu wọn sọkalẹ wá si ilẹ: o ti sọ ijọba ati awọn ijoye rẹ̀ di aimọ́. 3 O ti ke kuro ninu ibinu lile rẹ̀ gbogbo iwo Israeli: o ti fà ọwọ ọtún rẹ̀ pada kuro niwaju ọta, o si sun Jakobu bi iná iná, ti o jẹ run yikaká. 4 O ti fa ọrun rẹ̀ bi ọta: o fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ duro bi ọta, o si pa gbogbo eyiti o dùn si oju ni agọ́ ọmọbinrin Sioni: o dà irunu rẹ̀ jade bi iná. 5 Oluwa dabi ọta: o ti gbe Israeli mì, o ti gbe gbogbo ãfin rẹ̀ mì; 6 O si ti fi agbara gbà agọ́ rẹ̀ kuro, bi ẹnipe ti ọgba: o ti wó ibi ajọ rẹ̀ jẹ: Oluwa ti mu ki a gbagbe ajọ mimọ́ ati ọjọ isimi ni Sioni, o si ti kẹgan ninu irunu rẹ̀. bínú ọba àti àlùfáà. 7 Oluwa ti ṣá pẹpẹ rẹ̀ nù, o ti korira ibi-mimọ́ rẹ̀, o ti fi odi ãfin rẹ̀ le ọwọ ọta; nwọn ti pariwo ni ile Oluwa, bi li ọjọ ajọ. 8 Oluwa ti pinnu lati wó odi ọmọbinrin Sioni run: o ti nà okùn kan, kò si fà ọwọ́ rẹ̀ sẹhin kuro ninu iparun: nitorina o mu odi ati odi lati pohùnrére; wñn sðkalÆ. 9 Awọn ẹnu-bode rẹ̀ li a ti rì sinu ilẹ; o ti run, o si ti wó ọpá idabu rẹ̀: ọba rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀ wà lãrin awọn Keferi: ofin kò si mọ; awọn woli rẹ̀ pẹlu kò ri iran lati ọdọ Oluwa wá. 10 Awọn àgba ọmọbinrin Sioni joko lori ilẹ, nwọn si dakẹ: nwọn ti da erupẹ si ori wọn; nwọn ti fi aṣọ-ọ̀fọ di ara wọn: awọn wundia Jerusalemu fi ori wọn balẹ. 11 Ojú mi ṣubú pẹ̀lú omijé, inú mi dàrú,ẹ̀dọ̀ mi sì dà sórí ilẹ̀,nítorí ìparun ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi; nitori awọn ọmọ ati awọn ọmọ ẹnu-ọmu ti njẹ ni ita ilu naa. 12 Nwọn wi fun iya wọn pe, Nibo li ọkà ati ọti-waini wà? nígbà tí wọ́n bú bí àwọn tí ó gbọgbẹ́ ní ìgboro ìlú, nígbà tí a tú ọkàn wọn sí àyà ìyá wọn. 13 Kili emi o mu ṣe ẹlẹri fun ọ? Kili emi o fi ọ wé, iwọ ọmọbinrin Jerusalemu? kili emi o ba ọ dọgba, ki emi ki o le tù ọ ninu, iwọ wundia ọmọbinrin Sioni? nitori tõkan rẹ tobi bi okun: tani le mu ọ larada? 14. Awọn woli rẹ ti ri ohun asan ati asan fun ọ: nwọn kò si fi ẹ̀ṣẹ rẹ hàn, lati yi igbekun rẹ pada; ṣugbọn emi ti ri ẹru eke fun ọ ati awọn idi ifipalẹ. 15 Gbogbo awọn ti nkọja li ọwọ́ si ọ; nwọn si nmì ori wọn si ọmọbinrin Jerusalemu, wipe, Eyi ha ni ilu ti enia npè ni pipé ẹwà, ayọ̀ gbogbo aiye?