Skip to main content

Yoruba - The Book of Judges

Page 1

Awọn onidajọ ORI 1 1 O SI ṣe lẹhin ikú Joṣua, ni awọn ọmọ Israeli bère lọwọ OLUWA, wipe, Tani yio tète gòke tọ̀ awọn ara Kenaani gòke lọ fun wa, lati bá wọn jà? 2 OLUWA si wipe, Juda yio gòke lọ: sa wò o, emi ti fi ilẹ na le e lọwọ. 3 Juda si wi fun Simeoni arakunrin rẹ̀ pe, Ba mi gòke lọ si ilẹ mi, ki awa ki o le bá awọn ara Kenaani jà; èmi náà yóò sì bá ọ lọ sí ìpín rẹ. Símónì sì bá a lọ. 4 Juda si gòke lọ; OLUWA si fi awọn ara Kenaani ati awọn Perissi le wọn lọwọ: nwọn si pa ẹgbarun ọkunrin ninu wọn ni Beseki. 5 Nwọn si ri Adoni-beseki ni Beseki: nwọn si ba a jà, nwọn si pa awọn ara Kenaani ati awọn Perissi. 6 Ṣugbọn Adonibeseki sá; nwọn si lepa rẹ̀, nwọn si gbá a, nwọn si ke àtampako rẹ̀ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀ nla. 7 Adonibeseki si wipe, ãdọrin ọba, ti a ke atampako ati ti ẹsẹ̀ wọn kuro, nwọn si kó onjẹ wọn labẹ tabili mi: gẹgẹ bi mo ti ṣe, bẹ̃li Ọlọrun san a fun mi. Nwọn si mu u wá si Jerusalemu, nibẹ ni o si kú. 8 Awọn ọmọ Juda si ti ba Jerusalemu jà, nwọn si ti gbà a, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tina ilu na. 9 Lẹ́yìn náà ni àwọn ọmọ Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani jà, tí wọn ń gbé ní orí òkè, ati ní gúúsù, ati ní àfonífojì. 10 Juda si lọ bá awọn ara Kenaani ti ngbe Hebroni: (njẹ́ Hebroni nigba atijọ ni Kiriat-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai. 11 Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ bá àwọn ará Débírì jà: 12 Kalebu si wipe, Ẹnikẹni ti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si gbà a, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya. 13 Otnieli ọmọ Kenasi, aburo Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya. 14. O si ṣe, nigbati o tọ̀ ọ wá, o mu u lati bère oko lọdọ baba rẹ̀: o si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ? 15 On si wi fun u pe, Fun mi li ibukún: nitoriti iwọ ti fi ilẹ gusu fun mi; fún mi ní orísun omi pẹ̀lú. Kalebu si fun u ni isun oke ati isun isalẹ. 16 Ati awọn ọmọ Keni, ana Mose, gòke lati ilu ọpẹ lọ pẹlu awọn ọmọ Juda si ijù Juda, ti o wà ni ìha gusù ti Aradi; nwọn si lọ, nwọn si joko lãrin awọn enia. 17 Juda si bá Simeoni arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si pa awọn ara Kenaani ti ngbé Sefati, nwọn si run u patapata. Ati awọn orukọ ti awọn ilu ti a npe ni Horma. 18. Juda si gbà Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Askeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀. 19 OLUWA si wà pẹlu Juda; ó sì lé àwọn olùgbé òkè ńlá náà jáde; ṣugbọn kò lè lé àwọn ará àfonífojì náà jáde, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun irin. 20 Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: o si lé awọn ọmọ Anaki mẹta jade nibẹ̀. 21 Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi ngbé pẹlu awọn ọmọ Benjamini ni Jerusalemu titi di oni. 22 Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu gòke lọ si Beteli: OLUWA si wà pẹlu wọn.

23 Àwọn ará ilé Jósẹ́fù sì ránṣẹ́ láti ṣe àpèjúwe Bẹ́tẹ́lì. (Nísisìyí orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ jẹ́ Lúsì.) 24. Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ. 25 Nigbati o si fi ẹnu-ọ̀na ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jẹ ki ọkunrin na ati gbogbo idile rẹ̀ lọ. 26 Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn ara Hitti, o si tẹ ilu kan dó, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyiti iṣe orukọ rẹ̀ titi di oni. 27. Bẹ̃ni Manasse kò lé awọn ara Betṣeani jade, ati awọn ilu rẹ̀, tabi Taanaki, ati awọn ilu rẹ̀, tabi awọn ara Dori, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Ibleamu, ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megido, ati awọn ilu rẹ̀: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na. 28 O si ṣe, nigbati Israeli di alagbara, nwọn si mu awọn ara Kenaani fun u li ẹsan, nwọn kò si lé wọn jade patapata. 29 Bẹ̃ni Efraimu kò lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani joko lãrin wọn ni Geseri. 30 Bẹ̃ni Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahaloli; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si di ẹrú. 31. Bẹ̃ni Aṣeri kò lé awọn ara Akko jade, tabi awọn ara Sidoni, tabi awọn ara Ahlabu, tabi awọn ara Aksibu, tabi awọn ara Helba, tabi ti Afiki, tabi awọn ara Rehobu: 32 Ṣugbọn awọn ara Aṣeri ngbé ãrin awọn ara Kenaani, awọn ara ilẹ na: nitoriti nwọn kò lé wọn jade. 33 Naftali kò si lé awọn ara Betṣemeṣi jade, ati awọn ara Bet-anati; ṣugbọn o ngbe ãrin awọn ara Kenaani, awọn ti ngbe ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Betṣemeṣi ati ti Betani di iranṣẹ fun wọn. 34 Awọn ọmọ Amori si fi agbara mu awọn ọmọ Dani sori òke: nitoriti nwọn kò jẹ ki wọn sọkalẹ wá si afonifoji. 35 Ṣugbọn awọn ara Amori nfẹ joko lori òke Heresi ni Ajaloni, ati ni Ṣalbimu: ṣugbọn ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹrú. 36 Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè lọ sí Akrabbimu, láti àpáta lọ sókè. ORI 2 1 ANGẸLI OLUWA si gòke lati Gilgali lọ si Bokimu, o si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ na ti mo ti bura fun awọn baba nyin; mo si wipe, Emi kì yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai. 2 Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe eyi? 3 Nitorina emi pẹlu wipe, Emi kì yio lé wọn jade kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o dabi ẹgún ni ìha nyin, awọn oriṣa wọn yio si di ikẹkun fun nyin. 4 O si ṣe, nigbati angẹli Oluwa sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun. 5 Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si rubọ nibẹ̀ si OLUWA. 6 Nigbati Joṣua si ti jẹ ki awọn enia na ki o lọ, awọn ọmọ Israeli si lọ olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀ lati gbà ilẹ na. 7 Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti nwọn ti ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. 8 Jóṣúà ọmọ Núnì, ìránṣẹ́ Olúwa sì kú nígbà tí ó jẹ́ ẹni àádọ́fà ọdún.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of Judges by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu