Skip to main content

Yoruba - The Book of Exodus

Page 1

Eksodu ORI 1 1 NJẸ wọnyi li orukọ awọn ọmọ Israeli, ti o wá si Egipti; olukuluku ati awọn ara ile rẹ̀ wá pẹlu Jakobu. 2 Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì àti Júdà. 3 Issakari, Sebuluni, ati Benjamini; 4 Dani, ati Naftali, Gadi, ati Aṣeri. 5 Ati gbogbo ọkàn ti o ti inu Jakobu jade jẹ ãdọrin ọkàn: nitoriti Josefu ti wà ni Egipti na. 6 Josefu si kú, ati gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo iran na. 7 Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀ si i lọpọlọpọ, nwọn si rẹ̀ si i, nwọn si di alagbara; ilẹ̀ náà sì kún fún wọn. 8 Njẹ ọba titun kan dide lori Egipti, ti kò mọ̀ Josefu. 9 Ó sì wí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé, “Wò ó, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pọ̀, wọ́n sì lágbára jù wá lọ. 10 Wá, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n bá wọn lò; ki nwọn ki o má ba pọ̀ si i, nigbati ogun kan ba si bọ́, nwọn a da pẹlu awọn ọtá wa, nwọn si ba wa jà, ki nwọn ki o le jade kuro ni ilẹ na. 11 Nítorí náà, wọ́n yan àwọn akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti fi ẹrù wọn pọ́n wọn lójú. Wọ́n kọ́ ìlú ìṣúra fún Farao, Pitomu ati Raamusi. 12 Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ń pọ́n wọn lójú tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i tí wọ́n sì ń dàgbà sí i. Ìbànújẹ́ sì bá wọn nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 13 Awọn ara Egipti si mu awọn ọmọ Israeli sìn pẹlu lile: . 15 Ọba Egipti si sọ fun awọn iyãgbà Heberu, orukọ ekini ni Ṣifra, ati orukọ ekeji njẹ Pua: 16 O si wipe, Nigbati ẹnyin ba nṣe iṣẹ iyãgbà si awọn obinrin Heberu, ti ẹnyin ba si ri wọn lori apoti; bi o ba ṣe ọmọkunrin, njẹ ki ẹnyin ki o pa a: ṣugbọn bi o ba ṣe ọmọbinrin ni, njẹ on o yè. 17 Ṣugbọn awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, nwọn kò si ṣe gẹgẹ bi ọba Egipti ti paṣẹ fun wọn, ṣugbọn nwọn gbà awọn ọmọkunrin là. 18. Ọba Egipti si pè awọn iyãgbà na, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe nkan yi, ti ẹnyin si da awọn ọmọkunrin si? 19 Awọn iyãgbà si wi fun Farao pe, Nitoriti awọn obinrin Heberu kò dabi awọn obinrin Egipti; nitoriti nwọn wà lãye, nwọn si bi wọn ki awọn iyãgbà wọle tọ̀ wọn wá. 20 Nitorina Ọlọrun ṣe rere fun awọn iyãgbà na: awọn enia si di pupọ̀, nwọn si di alagbara gidigidi. 21 O si ṣe, nitoriti awọn iyãgbà bẹ̀ru Ọlọrun, o si kọ́ ile fun wọn. 22 Farao si paṣẹ fun gbogbo awọn enia rẹ̀, wipe, Gbogbo ọmọkunrin ti a bi ni ki ẹnyin ki o sọ sinu odò, ati gbogbo ọmọbinrin li ẹnyin o si gbà lãye. ORI 2 1 Ọkùnrin ará ilé Léfì kan sì lọ, ó sì fẹ́ ọmọbìnrin Léfì kan ní aya. 2 Obinrin na si yún, o si bí ọmọkunrin kan: nigbati o si ri i pe, ọmọ rere li on, o fi i pamọ́ li oṣù mẹta. 3 Nigbati kò si le fi i pamọ́ mọ́, o si gbé apoti ẽri kan fun u, o si fi ọ̀da ati ọ̀dada ṣan ẹ, o si fi ọmọ na sinu rẹ̀; ó sì gbé e kalẹ̀ sínú àwọn àsíá lẹ́bàá odò. 4 Arabinrin rẹ̀ si duro li òkere, lati mọ̀ ohun ti a o ṣe si i.

5 Ọmọbinrin Farao si sọkalẹ wá lati wẹ̀ li odò; awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ si nrìn li ẹba odò; Nígbà tí ó sì rí àpótí náà láàárín àsíá, ó rán ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ lọ gbé e wá. 6 Nigbati o si ṣí i, o ri ọmọ na: si kiyesi i, ọmọ-ọwọ na nsọkun. O si ṣãnu fun u, o si wipe, Eyi li ọkan ninu awọn ọmọ Heberu. 7 Arabinrin rẹ̀ si wi fun ọmọbinrin Farao pe, Ki emi ki o pè ọ, olutọju awọn obinrin Heberu, ki o le tọ́ ọmọ na fun ọ? 8 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Lọ. Ọmọbìnrin náà sì lọ pe ìyá ọmọ náà. 9 Ọmọbinrin Farao si wi fun u pe, Mú ọmọ yi lọ, ki o si tọ́ ọ fun mi, emi o si san ọ̀ya rẹ fun ọ. Obinrin na si mú ọmọ na, o si tọ́ ọ. 10 Ọmọ na si dàgba, o si mu u tọ̀ ọmọbinrin Farao wá, on si di ọmọ rẹ̀. O si sọ orukọ rẹ̀ ni Mose: o si wipe, Nitoriti mo fà a jade ninu omi. 11 O si ṣe li ọjọ́ wọnni, nigbati Mose dàgba, o jade tọ̀ awọn arakunrin rẹ̀ lọ, o si wò ẹrù wọn: o si ṣe amí ara Egipti kan, o si kọlù Heberu kan, ọkan ninu awọn arakunrin rẹ̀. 12 O si wò ìhin ati ọ̀hún, nigbati o si ri pe kò si ẹnikan, o pa ara Egipti na, o si fi i pamọ́ sinu iyanrin. 13 Nigbati o si jade ni ijọ́ keji, si kiyesi i, awọn ọkunrin Heberu meji mba ara wọn jà: o si wi fun ẹniti o ṣe buburu pe, Ẽṣe ti iwọ fi nlù ẹgbẹ́ rẹ? 14 On si wipe, Tani fi ọ ṣe olori ati onidajọ lori wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ijipti? Mose si bẹ̀ru, o si wipe, Lõtọ a mọ̀ nkan yi. 15 Nigbati Farao si gbọ́ nkan yi, o wá ọ̀na ati pa Mose. Ṣugbọn Mose sá kuro niwaju Farao, o si joko ni ilẹ Midiani: o si joko leti kanga kan. 16 Àlùfáà Mídíánì sì ní ọmọbìnrin méje: wọ́n sì wá pọn omi, wọ́n sì kún ìṣàn omi láti fi omi fún agbo ẹran baba wọn. 17 Awọn oluṣọ-agutan si wá, nwọn si lé wọn lọ: ṣugbọn Mose dide duro, o ràn wọn lọwọ, o si fun agbo-ẹran wọn. 18 Nigbati nwọn si tọ̀ Reueli baba wọn wá, o si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi dé li oni? 19 Nwọn si wipe, Ara Egipti kan gbà wa li ọwọ́ awọn oluṣọ-agutan, o si fa omi to fun wa pẹlu, o si fun agbo-ẹran na. 20 O si wi fun awọn ọmọbinrin rẹ̀ pe, Ati nibo li o wà? ẽṣe ti ẹnyin fi fi ọkunrin na silẹ? pè é, kí ó lè jẹ oúnjẹ. 21 Mose si yþ lati mã bá ọkunrin na gbé: o si fi Sippora ọmọbinrin rẹ̀ fun Mose. 22 On si bi ọmọkunrin kan fun u, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Gerṣomu: nitoriti o wipe, Emi ti ṣe atipo ni ilẹ ajeji. 23 O si ṣe lẹhin ọjọ na, ọba Egipti kú: awọn ọmọ Israeli si kẹdùn nitori oko-ẹrú, nwọn si kigbe, igbe wọn si gòke tọ̀ Ọlọrun wá nitori oko-ẹrú. 24 Ọlọrun si gbọ́ irora wọn, Ọlọrun si ranti majẹmu rẹ̀ pẹlu Abrahamu, pẹlu Isaaki, ati pẹlu Jakobu. 25 Ọlọrun si wò awọn ọmọ Israeli, Ọlọrun si fiyesi wọn. ORI 3 1 MOSE si pa agbo-ẹran Jetro ana rẹ̀, alufa Midiani mọ́: o si mú agbo-ẹran na lọ si ẹ̀hin ijù, o si wá si òke Ọlọrun, ani si Horebu. 2 Angeli OLUWA na si farahàn a ninu ọwọ́ iná lati ãrin igbẹ́: o si wò, si kiyesi i, igbo na ti njó, igbẹ́ na kò si run. 3 Mose si wipe, Emi o yipada nisisiyi, emi o si wò oju nla yi, idi ti igbẹ́ kò fi jóna.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of Exodus by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu