Esteri
22 Nitoriti o fi iwe ranṣẹ si gbogbo ìgberiko ọba, si gbogbo ìgberiko gẹgẹ bi iwe rẹ̀, ati si olukuluku enia gẹgẹ bi ède wọn, ki olukuluku ki o le jọba ni ile ara rẹ̀, ki a si ma tẹjade gẹgẹ bi ède olukuluku.
ORI 1
ORI 2
1 O SI ṣe li ọjọ Ahaswerusi, (eyi ni Ahaswerusi ti o jọba, lati India ani titi de Etiopia, lori ãdọfa ìgberiko:) 2 Pe li ọjọ wọnni, nigbati Ahaswerusi ọba joko lori itẹ ijọba rẹ̀, ti o wà ni ãfin Ṣuṣani; 3 Li ọdun kẹta ijọba rẹ̀, o sè àse fun gbogbo awọn ijoye rẹ̀ ati awọn iranṣẹ rẹ̀; agbára Persia àti Media, àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè ìgbèríko wà níwájú rẹ̀. 4 Nigbati o fi ọrọ̀ ijọba rẹ̀ ti o li ogo hàn, ati ọlá ọlanla rẹ̀ li ọjọ pipọ, ani ọgọsan ọjọ. 5 Nígbà tí àwọn ọjọ́ wọ̀nyí sì pé, ọba se àsè fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Ṣúṣánì ààfin, àti àgbà àti kékeré, fún ọjọ́ méje, ní àgbàlá àgbàlá ààfin ọba; 6 Nibiti o wà funfun, alawọ ewe, ati aṣọ-alaró, aṣọ-tita, ti a fi okùn ọ̀gbọ daradara ati elesè-àluko dì mọ́ oruka fadaka ati ọwọ̀n okuta didan: awọn ibusun wọnni jẹ́ wurà ati fadakà, li ori pète-pupa, ati aṣọ-alaró, ati funfun, ati dudu, okuta didan. 7 Wọ́n sì fún wọn ní ohun èlò wúrà mu, (àwọn ohun èlò náà yàtọ̀ sí ara wọn,) àti wáìnì ọba ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba. 8 Ati mimu na wà gẹgẹ bi ofin; kò si ẹniti o fi agbara mu: nitori bẹ̃ni ọba ti fi aṣẹ fun gbogbo awọn olori ile rẹ̀, ki nwọn ki o le ṣe gẹgẹ bi ifẹ olukuluku. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lù, Fáṣítì ayaba se àsè fún àwọn obìnrin ní ilé ọba tí ó jẹ́ ti Ahaswerusi ọba. 10 Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọtí wáìnì mú inú ọba dùn, ó pàṣẹ fún Mehumani, Bisita, Harbona, Bigta, Abagita, Setari, àti Karkasi, àwọn ìwẹ̀fà méje tí ń sìn níwájú Ahaswerusi ọba. 11 Lati mu Faṣti ayaba wá siwaju ọba ti on ti ade ọba, lati fi ẹwà rẹ̀ hàn awọn enia ati awọn ijoye: nitori o li ẹwà lati wò. 12 Ṣugbọn Faṣti ayaba kọ̀ lati wá nipa aṣẹ ọba lati ọwọ́ awọn ìwẹfa rẹ̀: nitorina ni ọba binu gidigidi, ibinu rẹ̀ si ru ninu rẹ̀. 13 Nigbana ni ọba wi fun awọn amoye, ti o mọ̀ igba, (nitori bẹ̃ni iṣe ọba ri si gbogbo awọn ti o mọ̀ ofin ati idajọ: 14 Ẹniti o tẹle e ni Karṣena, Ṣetari, Admata, Tarṣiṣi, Meresi, Marsena, ati Memukani, awọn ijoye meje ti Persia ati Media, ti o ri oju ọba, ti o si joko ni akọkọ ni ijọba;) 15 Kili awa o ṣe si Faṣti ayaba gẹgẹ bi ofin, nitoriti kò pa aṣẹ Ahaswerusi ọba mọ́ lati ọwọ awọn ìwẹfa? 16 Memukani si dahùn niwaju ọba ati awọn ijoye pe, Faṣti ayaba kò ṣẹ̀ si ọba nikanṣoṣo, ṣugbọn si gbogbo awọn ijoye pẹlu, ati si gbogbo enia ti o wà ni gbogbo ìgberiko Ahaswerusi ọba. 17 Nitori iṣe iṣe ayaba yi yio kàn gbogbo awọn obinrin, tobẹ̃ ti ọkọ wọn yio fi gàn li oju wọn, nigbati nwọn o si ròhin pe, Ahaswerusi ọba paṣẹ pe ki a mu Faṣti ayaba wá siwaju rẹ̀, ṣugbọn on kò wá. 18 Bẹ̃ gẹgẹ li awọn obinrin Persia ati Media yio si wi li oni fun gbogbo awọn ijoye ọba, ti nwọn ti gbọ́ iṣe ayaba. Báyìí ni ẹ̀gàn àti ìbínú yóò pọ̀jù. . kí ọba sì fi oyè ọba fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ. 20 Ati nigbati a ba si kede aṣẹ ọba ti on o pa ni gbogbo ijọba rẹ̀, (nitori pe o pọ̀,) gbogbo awọn obinrin ni yio fi ọlá fun ọkọ wọn, ati àgba ati ewe. 21 Ọ̀rọ na si dara loju ọba ati awọn ijoye; Ọba si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ Memukani:
1 LẸHIN nkan wọnyi, nigbati ibinu Ahaswerusi ọba rọ, o ranti Faṣti, ati ohun ti o ṣe, ati aṣẹ ti a ti palaṣẹ si i. 2 Nigbana ni awọn iranṣẹ ọba ti nṣe iranṣẹ fun u wipe, Jẹ ki a wá awọn wundia arẹwà fun ọba. 3 Kí ọba sì yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo ìgbèríko ìjọba rẹ̀, kí wọ́n lè kó gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin arẹwà jọ sí Ṣúṣánì ààfin, sí ilé àwọn obìnrin, sí abẹ́ àbójútó Hege ìwẹ̀fà ọba, olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a sì fi ohun ìwẹ̀nùmọ́ wọn fún wọn. 4 Ki wundia na ti o wù ọba ki o jẹ ayaba ni ipò Faṣti. Nkan na si dara loju ọba; ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. 5 Njẹ ni Ṣuṣani ãfin, ara Juda kan wà, orukọ rẹ̀ a ma jẹ Mordekai, ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ara Benjamini; 6 Ẹniti a ti kó ni Jerusalemu pẹlu igbekun ti a ti kó lọ pẹlu Jekoniah ọba Juda, ti Nebukadnessari ọba Babeli ti ko lọ. 7 O si tọ́ Hadassa dagba, eyini ni, Esteri, ọmọbinrin arakunrin baba rẹ̀: nitoriti kò ni baba, bẹ̃ni kò si ni iya, iranṣẹbinrin na si li ẹwà, o si li arẹwà; ti Mordekai, nigbati baba ati iya rẹ̀ kú, o mú fun ọmọbinrin on tikararẹ̀. 8 O si ṣe, nigbati a gbọ́ aṣẹ ọba ati aṣẹ rẹ̀, ati nigbati a pe ọ̀pọlọpọ wundia jọ si Ṣuṣani ãfin, si abẹ́ Hegai, a si mú Esteri pẹlu wá si ile ọba, si ọwọ́ Hegai, olutọju awọn obinrin. 9 Ọmọbinrin na si wù u, o si ri ore-ọfẹ gbà lọdọ rẹ̀; ó sì yára fún un ní ohun ìwẹ̀nùmọ́, pẹ̀lú ohun tí í ṣe tirẹ̀, àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin méje tí ó yẹ láti fi fún un, láti ilé ọba wá: ó sì fi òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ sí ipò tí ó dára jùlọ ní ilé àwọn obìnrin. 10 Esteri kò ti fi awọn enia rẹ̀ ati awọn ibatan rẹ̀ hàn: nitoriti Mordekai ti paṣẹ fun u pe ki o máṣe fi i hàn. 11 Mordekai a si ma rìn lojojumọ niwaju àgbala ile awọn obinrin, lati mọ̀ bi Esteri ti ṣe, ati bi yio ti ṣe e. 12 Njẹ nigbati gbogbo wundia ba de lati wọle tọ Ahaswerusi ọba lọ, lẹhin igbati o ti pé oṣù mejila, gẹgẹ bi iṣe awọn obinrin, (nitori bẹ̃li ọjọ ìwẹnumọ́ wọn pe, oṣù mẹfa pẹlu oróro ojia, ati oṣù mẹfa pẹlu õrùn didùn, ati pẹlu ohun miran fun ìwẹnumọ́ awọn obinrin;) 13 Bayi li gbogbo wundia wá si ọdọ ọba; ohunkohun ti o bère li a fi fun u lati ba a lọ lati ile awọn obinrin lọ si ile ọba. 14. Li aṣalẹ li o si lọ, ati ni ijọ́ keji o pada sinu ile keji ti awọn obinrin, si ọwọ́ Ṣaṣgasi, ìwẹfa ọba, ti nṣọ́ awọn àlè: on kò wọle tọ̀ ọba wá mọ́, bikoṣepe inu ọba dùn si i, ati pe a pè e li orukọ. 15 Njẹ nigbati Esteri, ọmọbinrin Abihaili, arakunrin Mordekai, ti o mu u fun ọmọbinrin rẹ̀, de lati wọle tọ̀ ọba lọ, on kò bère ohunkohun bikoṣe ohun ti Hegai ìwẹfa ọba, olutọju awọn obinrin, ti yàn. Esteri si ri ojurere li oju gbogbo awọn ti o wò o. 16 Bẹ̃li a mu Esteri lọ sọdọ Ahaswerusi ọba sinu ile ọba li oṣù kẹwa, ti iṣe oṣù Tebeti, li ọdun keje ijọba rẹ̀. 17 Ọba si fẹ́ Esteri jù gbogbo awọn obinrin lọ, on si ri oreọfẹ ati ojurere li oju rẹ̀ jù gbogbo awọn wundia na lọ; bẹ̃li o fi ade ọba le e li ori, o si fi i ṣe ayaba ni ipò Faṣti.