Deuteronomi ORI 1 1 WỌNYI si li ọ̀rọ ti Mose sọ fun gbogbo Israeli ni ìha ihin Jordani ni ijù, ni pẹtẹlẹ li ọkánkán Okun Pupa, li agbedemeji Parani, ati Tofeli, ati Labani, ati Haserotu, ati Disahabu. 2 (Ìrin ọjọ́ mọ́kànlá ni ó wà láti Horebu ní ọ̀nà òkè Seiri títí dé Kadeṣi-Barnea.) 3 O si ṣe li ogoji ọdún, li oṣù kọkanla, li ọjọ́ kini oṣù na, ni Mose sọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti fi aṣẹ fun wọn; 4 Lẹ́yìn tí ó ti pa Sihoni ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé Heṣiboni, ati Ogu ọba Baṣani, tí ń gbé ní Astarotu ní Edrei. 5 Ní òdìkejì Jọ́dánì ní ilẹ̀ Móábù ni Mósè bẹ̀rẹ̀ sí kéde òfin yìí pé: 6 OLUWA Ọlọrun wa bá wa sọ̀rọ̀ ní òkè Horebu pé, “Ẹ ti gbé ní orí òkè yìí fún ìgbà pípẹ́. 7 Ẹ yipada, ki ẹ si lọ, ki ẹ si lọ si òke awọn ọmọ Amori, ati si gbogbo ibi ti o sunmọ ọ, ni pẹtẹlẹ, ni òke, ati ni afonifoji, ati ni ìha gusù, ati leti okun, si ilẹ awọn ara Kenaani, ati dé Lebanoni, titi dé odò nla nì, odò Euferate. 8 Kiyesi i, emi ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọle, ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, lati fi fun wọn ati fun iru-ọmọ wọn lẹhin wọn. 9 Emi si sọ fun nyin li akokò na, wipe, Emi kò le gbà nyin nikanṣoṣo; 10 OLUWA Ọlọrun nyin ti sọ nyin di pupọ̀, si kiyesi i, li oni ẹnyin dabi irawọ oju-ọrun li ọ̀pọlọpọ. 11 (OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín mú yín pọ̀ sí i ní ìgbà ẹgbẹrun, kí ó sì bukun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín!) 12 Báwo ni èmi nìkan ṣe lè ru ìdààmú yín, àti ẹrù yín, àti ìjà yín? 13 Ẹ mú àwọn ọlọ́gbọ́n ati olóye, tí a sì mọ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà yín, n óo sì fi wọ́n ṣe olórí yín. 14 Ẹnyin si da mi lohùn, ẹnyin si wipe, Ohun ti iwọ ti sọ, o dara fun wa lati ṣe. 15 Bẹ́ẹ̀ ni mo mú àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn ọlọ́gbọ́n àti ẹni mímọ́, mo sì fi wọ́n ṣe olórí yín, olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, àti olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, àwọn olórí àràádọ́ta, olórí mẹ́wàá mẹ́wàá, àti àwọn olórí nínú àwọn ẹ̀yà yín. 16 Mo si fi aṣẹ fun awọn onidajọ nyin li akokò na wipe, Ẹ gbọ́ ẹjọ́ lãrin awọn arakunrin nyin, ki ẹ si ṣe idajọ ododo lãrin olukuluku ati arakunrin rẹ̀, ati alejò ti mbẹ lọdọ rẹ̀. 17 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe ojuṣaju enia ni idajọ; ṣugbọn ẹnyin o gbọ́ ẹni kekere ati ẹni-nla; ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù ojú eniyan; nitoriti Ọlọrun ni idajọ na: ati ọ̀ran ti o ṣoro jù fun nyin, ẹ mu u tọ̀ mi wá, emi o si gbọ́. 18 Emi si palaṣẹ fun nyin li akokò na ohun gbogbo ti ẹnyin o ṣe. 19 Nígbà tí a kúrò ní Horebu, a la gbogbo aṣálẹ̀ ńlá tí ó ní ẹ̀rù já, tí ẹ rí ní ọ̀nà òkè àwọn ará Amori, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wa ti pàṣẹ fún wa. a sì dé Kadeṣi-Barnea. 20 Emi si wi fun nyin pe, Ẹnyin dé òke awọn ọmọ Amori, ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa. 21 Kiyesi i, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ ki o si gbà a, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; Má bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì. “
23 Ọ̀rọ na si dara loju mi: mo si mú ọkunrin mejila ninu nyin, ọkan ninu ẹ̀ya kan. 24 Nwọn si yipada nwọn si gòke lọ sori òke, nwọn si wá si afonifoji Eṣkolu, nwọn si ṣe amí rẹ̀. 25 Nwọn si mú ninu eso ilẹ na li ọwọ́ wọn, nwọn si mú u sọkalẹ tọ̀ wa wá, nwọn si mú ìhin pada fun wa, nwọn si wipe, Ilẹ rere ti OLUWA Ọlọrun wa fi fun wa ni. 26 Ṣugbọn ẹnyin kò fẹ gòke lọ, ṣugbọn ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA Ọlọrun nyin. 27 Ẹnyin si nkùn ninu agọ́ nyin, ẹnyin si wipe, Nitoriti OLUWA korira wa, li o ṣe mú wa jade lati ilẹ Egipti wá, lati fi wa le ọwọ́ awọn ọmọ Amori, lati pa wa run. 28 Nibo li awa o gòke lọ? awọn arakunrin wa ti rẹ̀ wa li ọkàn, wipe, Awọn enia na tobi, nwọn si ga jù wa lọ; àwọn ìlú ńláńlá, wọ́n sì mọ odi yíká ọ̀run; ati pẹlupẹlu awa ti ri awọn ọmọ Anaki nibẹ. 29 Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe bẹ̀ru wọn. 30 OLUWA Ọlọrun nyin, ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin; 31 Ati li aginjù, nibiti iwọ ti ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi enia ti ngbé ọmọ rẹ̀, ni gbogbo ọ̀na ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi. 32 Síbẹ̀, ẹ̀yin kò gba Olúwa Ọlọ́run yín gbọ́. . 34 OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe, 35 Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin buburu wọnyi ti iran buburu yi ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin. 36 Àfi Kalebu æmæ Jéfúnè; on o ri i, on li emi o si fi ilẹ na ti o ti tẹ̀ mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, nitoriti o tọ̀ OLUWA lẹhin patapata. 37 OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio wọ̀ inu rẹ̀ wọle. 38 Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ti o duro niwaju rẹ, on ni yio wọ̀ ibẹ̀ lọ: gbà a ni iyanju: nitori on ni yio mu Israeli ni i. 39 Pẹlupẹlu awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe ki nwọn ki o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti kò mọ̀ rere ati buburu li ọjọ na, nwọn o lọ sibẹ̀, nwọn o si fi i fun, nwọn o si gbà a. 40 Ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀yin, ẹ yípadà, kí ẹ sì mú ọ̀nà yín lọ sí aginjù ní ọ̀nà Òkun Pupa. 41 Nigbana li ẹnyin dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Nigbati olukuluku nyin si di ihamọra ogun rẹ̀ li àmure, ẹnyin mura lati gòke lọ sori òke na. 42 OLUWA si wi fun mi pe, Sọ fun wọn pe, Ẹ má gòke lọ, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe jà; nitoriti emi kò si lãrin nyin; ki a má ba lù nyin niwaju awọn ọtá nyin. 43 Nitorina ni mo ṣe sọ fun nyin; Ẹnyin kò si fẹ́ gbọ́, ṣugbọn ẹ ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA, ẹnyin si gòke lọ si ori òke pẹlu igberaga. 44 Awọn ọmọ Amori ti ngbé ori oke na si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, gẹgẹ bi oyin ti nṣe, nwọn si pa nyin run ni Seiri, ani dé Horma. 45 Ẹnyin si pada, ẹ si sọkun niwaju OLUWA; ṣugbọn OLUWA kò fẹ́ gbọ́ ohùn yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fetí sí yín. 46 Bẹ̃ni ẹnyin joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pipọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.