2 Samueli ORI 1 1 O SI ṣe lẹhin ikú Saulu, nigbati Dafidi si ti ipakupa awọn ara Amaleki pada, Dafidi si joko ni ijọ meji ni Siklagi; 2 O si ṣe ni ijọ́ kẹta, si kiyesi i, ọkunrin kan ti ibudó jade lati ọdọ Saulu wá, ti on ti aṣọ rẹ̀ ya, ati erupẹ li ori rẹ̀: o si ṣe, nigbati o de ọdọ Dafidi, o ṣubu lulẹ, o si tẹriba. 3 Dafidi si wi fun u pe, Nibo ni iwọ ti ti wá? On si wi fun u pe, Ninu ibudó Israeli li emi ti bọ́. 4 Dafidi si wi fun u pe, Ọ̀ran na ti ri? Mo bẹ ọ, sọ fun mi. On si dahùn wipe, Awọn enia na sá fun ogun na, ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn enia na ti ṣubu ti nwọn si kú; Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ sì ti kú pẹlu. 5 Dafidi si wi fun ọdọmọkunrin na ti o sọ fun u pe, Bawo ni iwọ ṣe mọ̀ pe Saulu ati Jonatani ọmọ rẹ̀ ti kú? 6 Ọdọmọkunrin na ti o sọ fun u wipe, Bi mo ti ṣe lojiji li òke Gilboa, kiyesi i, Saulu fi ara tì ọ̀kọ rẹ̀; si kiyesi i, awọn kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin nlepa rẹ̀ kikan. 7 Nigbati o si wò ẹhin rẹ̀, o ri mi, o si ke pè mi. Emi si dahùn pe, Emi niyi. 8 O si wi fun mi pe, Tani iwọ iṣe? Mo si da a lohùn pe, Ara Amaleki ni mi. 9 O si tun wi fun mi pe, Emi bẹ̀ ọ, duro tì mi, ki o si pa mi: nitoriti ìrora dé ba mi, nitoriti ẹmi mi si wà lara mi sibẹ̀. 10 Mo si duro lori rẹ̀, mo si pa a, nitoriti mo mọ̀ pe kò le yè lẹhin igbati o ti ṣubu: mo si mú ade ti mbẹ li ori rẹ̀, ati ẹgba ti mbẹ li apa rẹ̀, mo si mu wọn wá ihin tọ̀ oluwa mi wá. 11 Dafidi si di aṣọ rẹ̀ mú, o si fà wọn ya; ati pẹlu gbogbo awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ. 12 Nwọn si ṣọ̀fọ, nwọn si sọkun, nwọn si gbàwẹ titi di aṣalẹ, fun Saulu, ati fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun awọn enia Oluwa, ati fun ile Israeli; nitoriti nwọn ti ipa idà ṣubu. 13 Dafidi si wi fun ọdọmọkunrin na ti o sọ fun u pe, Nibo ni iwọ ti wá? On si dahùn wipe, Ọmọ alejò kan li emi, ara Amaleki. 14 Dafidi si wi fun u pe, Bawo ni iwọ kò ṣe bẹ̀ru lati nà ọwọ́ rẹ lati pa ẹni-àmi-ororo Oluwa run? 15 Dafidi si pè ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin na, o si wipe, Sunmọ, ki o si kọlù u. Ó sì lù ú, ó sì kú. 16 Dafidi si wi fun u pe, Ẹjẹ rẹ ki o wà li ori rẹ; nitoriti ẹnu rẹ ti jẹri si ọ, wipe, Emi ti pa ẹni-àmi-ororo Oluwa. 17 Dáfídì sì pohùnréré ẹkún yìí lórí Ṣọ́ọ̀lù àti lórí Jónátanì ọmọ rẹ̀. 18 (O si paṣẹ fun wọn lati ma kọ́ awọn ọmọ Juda li ọrùn ọrun: kiyesi i, a ti kọ ọ sinu iwe Jaṣeri.) 19 A pa ẹwà Israeli lori ibi giga rẹ: bawo ni awọn alagbara ti ṣubu! 20 Máṣe sọ ọ ni Gati, máṣe kede rẹ̀ ni ita Askeloni; ki awọn ọmọbinrin Filistini má ba yọ̀, ki awọn ọmọbinrin awọn alaikọla ki o má ba yọ̀. 21 Ẹnyin òke Gilboa, máṣe jẹ ki ìrì má si, bẹ̃ni ki òjo ki o si rọ̀ sori nyin, tabi oko ọrẹ-ẹbọ: nitori nibẹ̀ li a ti sọ asà awọn alagbara sọnù, asà Saulu, bi ẹnipe a kò fi oróro yà a si. 22 Ọrun Jonatani kò yipada ninu ẹ̀jẹ̀ awọn ti a pa, ati ọrá awọn alagbara, bẹ̃ni idà Saulu kò pada li ọwọ́ ofo. 23 Saulu ati Jonatani li arẹwà, nwọn si dùn li aiye wọn, ati ni ikú wọn, nwọn kò yapa: nwọn yara jù idì lọ, nwọn si li agbara jù kiniun lọ.
24 Ẹnyin ọmọbinrin Israeli, ẹ sọkun nitori Saulu, ẹniti o fi aṣọ ododó wọ̀ nyin, ti o si fi ohun didùn miran wọ̀, ti o fi ohun ọṣọ́ wura si ara nyin. 25 Bawo ni awọn alagbara ti ṣubu li ãrin ogun! Jónátánì, a ti pa ọ́ ní àwọn ibi gíga rẹ. 26 Ibanujẹ ba mi nitori rẹ, Jonatani arakunrin mi: inu rẹ dùn si mi: ifẹ rẹ si mi jẹ iyanu, o kọja ifẹ obinrin lọ. 27 Bawo ni awọn alagbara ti ṣubu, ati ohun ija ti ṣegbe! ORI 2 1 O SI ṣe lẹhin eyi, ni Dafidi si bere lọdọ Oluwa, wipe, Ki emi ki o gòke lọ si ọkan ninu ilu Juda bi? OLUWA si wi fun u pe, Goke lọ. Dafidi si wipe, Nibo li emi o gòke lọ? On si wipe, Si Hebroni. 2 Dafidi si gòke lọ sibẹ̀, ati awọn obinrin rẹ̀ mejeji pẹlu, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili, aya Nabali, ara Karmeli. 3 Dafidi si mú awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti o wà lọdọ rẹ̀ gòke wá, olukuluku pẹlu ile rẹ̀: nwọn si ngbe ilu Hebroni. 4 Awọn ọkunrin Juda si wá, nwọn si fi Dafidi jọba nibẹ̀ lori ile Juda. Nwọn si sọ fun Dafidi pe, Awọn ọkunrin JabeṣiGileadi li awọn ti o sin Saulu. 5 Dafidi si ran onṣẹ si awọn ọkunrin Jabeṣi-Gileadi, o si wi fun wọn pe, Alabukún-fun li ẹnyin ti OLUWA, ti ẹnyin ti ṣe ore yi si oluwa nyin, ani fun Saulu, ẹnyin si ti sin i. 6 Njẹ nisisiyi ki OLUWA ki o ṣe ore ati otitọ fun nyin: emi pẹlu o si san oore yi fun nyin pẹlu, nitoriti ẹnyin ti ṣe nkan yi. 7 Njẹ nisisiyi, jẹ ki ọwọ́ nyin ki o le, ki ẹnyin ki o si jẹ akikanju: nitoriti Saulu oluwa nyin ti kú, ati pẹlu ile Juda pẹlu ti fi ororo yàn mi li ọba lori wọn. 8 Ṣugbọn Abneri ọmọ Neri, olori ogun Saulu, mu Iṣboṣeti ọmọ Saulu, o si mu u lọ si Mahanaimu; 9 O si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli. 10 Iṣiboṣeti ọmọ Saulu si jẹ ẹni ogoji ọdun nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli, o si jọba li ọdun meji. Ṣugbọn ilé Juda tẹ̀lé Dafidi. 11 Àkókò tí Dáfídì fi jọba ní Hébúrónì lórí ilé Júdà jẹ́ ọdún méje àti oṣù mẹ́fà. 12 Abneri ọmọ Neri, ati awọn iranṣẹ Iṣboṣeti ọmọ Saulu si jade kuro ni Mahanaimu lọ si Gibeoni. . 14 Abneri si wi fun Joabu pe, Jẹ ki awọn ọdọmọkunrin dide nisisiyi, ki nwọn ki o si ṣere niwaju wa. Joabu si wipe, Jẹ ki nwọn dide. 15 Nigbana li awọn mejila dide, nwọn si gòke lati inu Benjamini, ti iṣe ti Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ati mejila ninu awọn iranṣẹ Dafidi. 16 Olukuluku wọn si di ọmọnikeji rẹ̀ li ori, nwọn si fi idà rẹ̀ bọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ̃ni nwọn jumọ ṣubu lulẹ: nitorina li a ṣe npè ibẹ na ni Helkati-hassurim, ti mbẹ ni Gibeoni. 17 Ogun kan si líle li ọjọ na; Wọ́n sì lu Ábínérì àti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì níwájú àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì. 18 Awọn ọmọ Seruia mẹta si mbẹ nibẹ̀, Joabu, ati Abiṣai, ati Asaheli: ẹsẹ Asaheli si fuyẹ bi abo abo-agutan igbẹ. 19 Asaheli si lepa Abneri; nígbà tí ó sì ń lọ, kò yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí sí òsì láti máa tọ Abneri lẹ́yìn. 20 Abneri si wò ẹhin rẹ̀, o si wipe, Iwọ Asaheli bi? On si dahùn wipe, Emi ni.