2 Ọba ORI 1 1 NIGBANA ni Moabu ṣọ̀tẹ si Israeli lẹhin ikú Ahabu. . 3 Ṣugbọn angẹli OLUWA sọ fún Elija, ará Tiṣibi pé, “Dìde, gòkè lọ pàdé àwọn ońṣẹ́ ọba Samaria, kí o sì sọ fún wọn pé, “Kì í ha ṣe nítorí pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli ni ẹ fi lọ bèèrè lọ́wọ́ Baalsebubu, oriṣa Ekroni? 4 Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa wi, Iwọ kì yio sọkalẹ lati ori akete na ti iwọ gùn, ṣugbọn nitõtọ iwọ o kú. Elijah si lọ. 5 Nigbati awọn onṣẹ na si pada tọ̀ ọ wá, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi yipada nisisiyi? 6 Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan gòke wá lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ tun yipada si ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Kò ha ṣe nitoriti kò sí Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni? nitorina iwọ ki yio sọ̀kalẹ lati ori akete na ti iwọ gùn, ṣugbọn nitõtọ iwọ o kú. 7 O si wi fun wọn pe, Irú ọkunrin wo li ẹniti o gòke wá ipade nyin, ti o si sọ ọ̀rọ wọnyi fun nyin? 8 Nwọn si da a lohùn wipe, Okunrin onirun li on, o si sán amure awọ mọ ẹgbẹ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni. 9 Nigbana ni ọba rán olori ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. O si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba ti wipe, Sọkalẹ wá. 10 Elijah si dahùn o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, njẹ ki iná ki o sọkalẹ lati ọrun wá, ki o si run iwọ ati ãdọta rẹ. Iná sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta rẹ̀ run. 11 O si tun rán olori ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Enia Ọlọrun, bayi li ọba ti wi, Sọkalẹ kánkán. 12 Elijah si dahùn o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọkalẹ lati ọrun wá, ki o si run iwọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọ́run sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, ó sì jó òun àti àádọ́ta rẹ̀ run. 13 O si tun rán olori ãdọta kẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori ãdọta kẹta si goke lọ, o si wá, o si kunlẹ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ẹmi mi, ati ẹmi ãdọta awọn iranṣẹ rẹ wọnyi ki o ṣe iyebiye li oju rẹ. 14 Kiyesi i, iná ti ọrun sọkalẹ wá, o si jo awọn olori ãdọta ãdọta iṣaju pẹlu ãdọta wọn: nitorina jẹ ki ẹmi mi ki o ṣe iyebiye li oju rẹ. 15 Angeli OLUWA na si wi fun Elijah pe, Sọ̀kalẹ pẹlu rẹ̀: máṣe bẹ̀ru rẹ̀. O si dide, o si ba a sọkalẹ lọ sọdọ ọba. 16 O si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti iwọ ti rán onṣẹ lati bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, kì iṣe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nítorí náà, o kò ní sọ̀kalẹ̀ lórí ibùsùn tí o gbé gùn, ṣugbọn kíkú ni o óo kú. 17 Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀ li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda; nítorí kò ní ọmọkùnrin. 18 Ati iyokù iṣe Ahasaya ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli? ORI 2 1 O SI ṣe, nigbati Oluwa nfẹ gbe Elijah lọ si ọrun ti on ti ìji, ni Elijah ba Eliṣa lọ ni Gilgali.
2 Elijah si wi fun Eliṣa pe, Emi bẹ̀ ọ, duro nihin; nítorí Yáhwè ti rán mi sí B¿t¿lì. Eliṣa si wi fun u pe, Bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ọkàn rẹ ti mbẹ lãye, emi kì yio fi ọ silẹ. Nítorí náà, wọ́n lọ sí Bẹ́tẹ́lì. 3 Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Beteli si jade tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ ha mọ̀ pe OLUWA yio mu oluwa rẹ kuro li ori rẹ li oni? On si wipe, Nitõtọ, emi mọ̀; ẹ pa ẹnu nyin mọ́. 4 Elijah si wi fun u pe, Eliṣa, emi bẹ̀ ọ, duro nihin; nítorí Yáhwè ti rán mi sí Jéríkò. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ọkàn rẹ ti wà lãye, emi kì yio fi ọ silẹ. Nítorí náà, wọ́n dé Jẹ́ríkò. 5 Awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko si tọ̀ Eliṣa wá, nwọn si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ pe OLUWA yio mu oluwa rẹ kuro li ori rẹ li oni? On si dahùn wipe, Bẹ̃ni, emi mọ̀; ẹ pa ẹnu nyin mọ́. 6 Elijah si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, duro nihin; nítorí Yáhwè ti rán mi sí Jñrdánì. On si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ọkàn rẹ ti wà lãye, emi kì yio fi ọ silẹ. Àwọn méjèèjì sì ń bá a lọ. 7 Aadọta ninu awọn ọmọ awọn woli si lọ, nwọn si duro li òkere rére: awọn mejeji si duro leti Jordani. 8 Èlíjà sì mú ẹ̀wù rẹ̀, ó sì fi wé e, ó sì lu omi náà, ó sì pín wọn sí méjì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì fi kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ. 9 O si ṣe, nigbati nwọn kọja, Elijah wi fun Eliṣa pe, Bère ohun ti emi o ṣe fun ọ, ki a to mu mi kuro lọdọ rẹ. Eliṣa si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ipín meji ẹmi rẹ ki o bà le mi. 10 On si wipe, Iwọ bère ohun lile: ṣugbọn bi iwọ ba ri mi nigbati a ba gbà mi lọwọ rẹ, yio ri bẹ̃ fun ọ; ṣugbọn bi bẹ̃kọ, kì yio ri bẹ̃. 11 O si ṣe, bi nwọn ti nlọ, ti nwọn nsọ̀rọ, si kiyesi i, kẹkẹ́ iná kan, ati ẹṣin iná si hàn, o si yà awọn mejeji si yà; Elijah si fi ìji gòke lọ si ọrun. 12 Eliṣa si ri i, o si kigbe pe, Baba mi, baba mi, kẹkẹ́ Israeli, ati awọn ẹlẹṣin rẹ̀. On ko si ri i mọ́: o si di aṣọ ara rẹ̀ mu, o si fà wọn ya si meji. 13 O si gbé agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀ pẹlu, o si pada, o si duro leti Jordani; 14 O si mú agbáda Elijah ti o bọ́ lọwọ rẹ̀, o si lù omi na, o si wipe, Nibo li Oluwa Ọlọrun Elijah wà? nigbati o si ti lu omi pẹlu, nwọn pin sihin ati sọhun: Eliṣa si rekọja. 15 Nigbati awọn ọmọ awọn woli ti o wà ni Jeriko ri i, nwọn wipe, Ẹmi Elijah bà le Eliṣa. Nwọn si wá ipade rẹ̀, nwọn si tẹriba fun u. 16 Nwọn si wi fun u pe, Wò o na, ãdọta ọkunrin alagbara mbẹ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ; awa bẹ̀ ọ, jẹ ki nwọn ki o lọ, ki nwọn si wá oluwa rẹ: bọya Ẹmi Oluwa ti gbe e soke, o si sọ ọ si ori òke kan, tabi sinu afonifoji kan. On si wipe, Ẹnyin kò gbọdọ rán. 17 Nigbati nwọn si rọ̀ ọ titi oju fi tì i, o wipe, Rán. Nitorina nwọn rán ãdọta ọkunrin; nwọn si wá ijọ mẹta, ṣugbọn nwọn kò ri i. 18 Nigbati nwọn si tun tọ̀ ọ wá, (nitori o duro ni Jeriko,) o si wi fun wọn pe, Emi kò ti wi fun nyin pe, Ẹ máṣe lọ? 19 Awọn ọkunrin ilu na si wi fun Eliṣa pe, Kiyesi i, emi bẹ̀ ọ, ipò ilu yi dara, bi oluwa mi ti ri: ṣugbọn omi na jẹ asan, ilẹ si yàgan. 20 O si wipe, Mu àwokòto titun kan fun mi wá, ki o si fi iyọ̀ sinu rẹ̀. Wọ́n sì gbé e wá fún un. 21 O si jade lọ si ibi isun omi, o si da iyọ̀ si ibẹ, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ti mu omi wọnyi sàn; kì yóò sí ikú mọ́ tàbí ilẹ̀ aṣálẹ̀ mọ́. 22 Bẹ̃ni omi na si ti san titi di oni, gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa ti o sọ.