Skip to main content

Yoruba - The Book of 1st Samuel the Prophet

Page 1

1 Samueli ORI 1 1 Ọkunrin kan si wà, ara Ramataimu-sofimu, ti òke Efraimu, orukọ rẹ̀ a si ma jẹ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ara Efrata: 2 O si li obinrin meji; orukọ ekini a ma jẹ Hana, orukọ ekeji si njẹ Penina: Penina si ni ọmọ, ṣugbọn Hanna kò ni ọmọ. 3 Ọkunrin yi si ma gòke lati ilu rẹ̀ lọ lọdọọdun lati sìn ati lati rubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ati awọn ọmọ Eli mejeji, Hofini ati Finehasi, awọn alufa Oluwa, wà nibẹ. 4 Nígbà tí ó tó àkókò tí Ẹlikénà ń rúbọ, ó fún Penina, aya rẹ̀, ati gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ní ìpín. 5 Ṣugbọn Hanna li o fi ipin ti o yẹ; nitoriti o fẹ Hana: ṣugbọn Oluwa ti sé inu rẹ̀. 6 Ọta rẹ̀ pẹlu si binu, nitoriti o le mu u binu, nitoriti Oluwa ti sé inu rẹ̀. 7 Ati gẹgẹ bi o ti nṣe bẹ̃ li ọdọdun, nigbati o gòke lọ si ile Oluwa, bẹ̃li o ṣe mu u binu; nitorina li o ṣe sọkun, kò si jẹun. 8 Nigbana ni Elkana ọkọ rẹ̀ wi fun u pe, Hanna, ẽṣe ti iwọ fi nsọkun? ẽṣe ti iwọ kò si jẹun? ẽṣe ti ọkàn rẹ fi bajẹ? Èmi kò ha sàn fún ọ ju ọmọkùnrin mẹ́wàá lọ? 9 Bẹ̃ni Hanna dide lẹhin igbati nwọn jẹun ni Ṣilo, ati lẹhin igbati nwọn ti mu yó. Eli alufa si joko lori ijoko lẹba opó tẹmpili Oluwa. 10 O si wà ninu kikoro ọkàn, o si gbadura si Oluwa, o si sọkun kikan. 11 O si jẹ́ ẹjẹ́, o si wipe, Oluwa awọn ọmọ-ogun, bi iwọ ba bojuwò ipọnju iranṣẹbinrin rẹ nitõtọ, ti iwọ o si ranti mi, ti iwọ kò si gbagbe iranṣẹbinrin rẹ, ṣugbọn iwọ o fi ọmọkunrin fun iranṣẹbinrin rẹ, nigbana li emi o fi fun OLUWA li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo, ti abẹ kì yio si wá si ori rẹ̀. 12 O si ṣe, bi o ti ngbàdura niwaju Oluwa, ni Eli si kiyesi ẹnu rẹ̀. 13 Njẹ Hanna, on sọ̀rọ li ọkàn rẹ̀; kìki ètè rẹ̀ li o nmì, ṣugbọn a kò gbọ́ ohùn rẹ̀; 14 Eli si wi fun u pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o mu yó? mu ọtiwaini rẹ kuro lọdọ rẹ. 15 Hanna si dahùn o si wipe, Bẹ̃kọ, oluwa mi, emi li obinrin ti ọkàn ibinujẹ: emi kò mu ọti-waini tabi ọti lile, ṣugbọn emi ti tú ọkàn mi silẹ niwaju Oluwa. 16. Máṣe ka iranṣẹbinrin rẹ si ọmọbinrin Beliali: nitori ninu ọ̀pọlọpọ aroye ati ibinujẹ mi li emi ti nsọ̀rọ titi di isisiyi. 17 Nigbana ni Eli dahùn o si wipe, Lọ li alafia: Ọlọrun Israeli si fi ẹ̀bẹ rẹ ti iwọ bère lọwọ rẹ̀ fun ọ. 18 On si wipe, Jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ri ore-ọfẹ li oju rẹ. Obinrin na si ba tirẹ̀ lọ, o si jẹun, oju rẹ̀ kò si bàjẹ́ mọ́. 19 Nwọn si dide ni kutukutu owurọ̀, nwọn si sìn niwaju OLUWA, nwọn si pada, nwọn si wá si ile wọn ni Rama: Elkana si mọ̀ Hanna aya rẹ̀; OLUWA si ranti rẹ̀. 20 O si ṣe, nigbati akokò si pé lẹhin ti Hana loyun, o si bí ọmọkunrin kan, o si sọ orukọ rẹ̀ ni Samueli, wipe, Nitoriti mo ti bère lọwọ Oluwa. 21 Ọkunrin na Elkana, ati gbogbo ile rẹ̀, si gòke lọ lati ru ẹbọ ọdun si OLUWA, ati ẹjẹ́ rẹ̀. 22 Ṣugbọn Hanna kò gòke lọ; nitoriti o wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Emi kì yio gòke lọ titi a o fi já ọmọ na li ẹnu ọmu, nigbana

li emi o mu u wá, ki o le farahàn niwaju OLUWA, ki o si joko nibẹ̀ lailai. 23. Elkana ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ṣe eyi ti o tọ́ li oju rẹ; duro titi iwọ o fi já a li ọmu; kiki OLUWA ki o fi idi ọ̀rọ rẹ̀ mulẹ. Obinrin na si joko, o si fun ọmọ rẹ̀ li ẹnu li ẹnu titi o fi já a li ẹnu ọmu. 24 Nigbati o si já a li ẹnu ọmu, o si mu u gòke lọ pẹlu rẹ̀, ti on ti akọmalu mẹta, ati efa iyẹfun kan, ati igo ọti-waini kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọdọmọde. 25 Nwọn si pa akọmalu kan, nwọn si mú ọmọ na tọ̀ Eli wá. 26 On si wipe, Oluwa mi, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, oluwa mi, emi li obinrin na ti o duro tì ọ nihin, ti ngbàdura si Oluwa. 27 Fun ọmọde yi ni mo gbadura; OLUWA si ti fun mi li ẹ̀bẹ mi ti mo bère lọwọ rẹ̀. 28 Nitorina emi pẹlu ti ya a fun Oluwa; Níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láàyè, a óo yá OLUWA. Ó sì sin Olúwa níbẹ̀. ORI 2 1 Hanna si gbadura, o si wipe, Aiya mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gbilẹ lori awọn ọta mi; nitoriti mo yọ̀ si igbala rẹ. 2 Kò sí ẹni mímọ́ bí Olúwa: nítorí kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àpáta kan bí Ọlọ́run wa. 3 Máṣe sọ̀rọ̀ lọpọlọpọ mọ́; máṣe jẹ ki igberaga ki o ti ẹnu nyin jade: nitori Oluwa li Ọlọrun ìmọ, ati nipa rẹ̀ li a fi wọ̀n iṣe. 4 A ṣẹ́ ọrun awọn alagbara, ati awọn ti o kọsẹ̀ li a fi agbara di amure. 5 Awọn ti o yó ti bẹ̀ ara wọn fun onjẹ; awọn ti ebi npa si dá, tobẹ̃ ti àgan bí meje; ati ẹniti o bi ọmọ pupọ̀ di alailagbara. 6 Oluwa pa, o si sọ di ãye: o mu sọkalẹ lọ si isa-okú, o si mu gòke lọ. 7 Oluwa mu talaka, o si sọ di ọlọrọ̀: o rẹ̀ silẹ, o si gbé soke. 8 O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbe alagbe soke lati inu ãtàn wá, lati fi wọn kalẹ lãrin awọn ọmọ-alade, ati lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori ti Oluwa ni ọwọ̀n aiye, o si ti fi aiye le wọn. 9 On o pa ẹsẹ awọn enia mimọ́ rẹ̀ mọ́, ati awọn enia buburu yio dakẹ ninu òkunkun; nítorí pé nípa agbára kò sí ènìyàn kankan. 10 A o fọ́ awọn ọta Oluwa tũtu; lati ọrun wá ni yio sán ãrá si wọn: Oluwa yio ṣe idajọ opin aiye; on o si fi agbara fun ọba rẹ̀, yio si gbé iwo ẹni-ororo rẹ̀ ga. 11 Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si ṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa. 12 Njẹ awọn ọmọ Eli li ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ OLUWA. 13 Àṣà àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé, nígbà tí ẹnikẹ́ni bá rúbọ, ìránṣẹ́ àlùfáà a máa wá, nígbà tí ẹran náà ti ń jóná, pẹ̀lú ìwọ̀ ẹran eyín mẹ́ta lọ́wọ́; 14 O si gún u sinu apẹ, tabi ìgò, tabi ìkòkò, tabi ìkoko; gbogbo ohun tí àwæn Åran náà mú gòkè wá ni àlùfáà mú fún ara rÆ. Bẹ̃ni nwọn ṣe ni Ṣilo si gbogbo awọn ọmọ Israeli ti o wá si ibẹ. 15. Pẹlupẹlu ki nwọn ki o to sun ọrá na, iranṣẹ alufa si wá, o si wi fun ọkunrin na ti o rubọ pe, Fi ẹran na fun alufa; nitoriti on kì yio ni ẹran sè lọwọ rẹ, bikoṣe pọn. 16 Bi ẹnikan ba si wi fun u pe, Máṣe jẹ ki nwọn ki o máṣe sun ọrá na nisisiyi, njẹ ki o si mu iye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana ni yio da a lohùn pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn iwọ o fi fun mi nisisiyi: bi bẹ̃kọ, emi o fi agbara gbà a. 17 Nitorina ẹ̀ṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si pọ̀ gidigidi niwaju OLUWA: nitoriti awọn enia korira ọrẹ-ẹbọ OLUWA.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook