Skip to main content

Yoruba - The Book of 1st Chronicles

Page 1

1 Kronika ORI 1 1 Ádámù, Ṣétì, Énọ́ṣì, 2 Kenani, Mahalaleli, Jeredi; 3 Hénókù, Mètúsélà, Lámékì, 4 Noa, Ṣemu, Hamu, ati Jafeti. 5 Awọn ọmọ Jafeti; Gomeri, ati Magogu, ati Madai, ati Jafani, ati Tubali, ati Meṣeki, ati Tirasi. 6 Ati awọn ọmọ Gomeri; Aṣkenasi, ati Rifati, ati Togama. 7 Ati awọn ọmọ Jafani; Eliṣa, ati Tarṣiṣi, Kittimu, ati Dodanimu. 8 Awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, Puti, ati Kenaani. 9 Ati awọn ọmọ Kuṣi; Seba, ati Hafila, ati Sabta, ati Raama, ati Sabteka. Ati awọn ọmọ Raama; Ṣeba, ati Dedani. 10 Kuṣi si bi Nimrodu: o bẹ̀rẹ si di alagbara li aiye. 11 Misraimu si bi Ludimu, ati Anamimu, ati Lehabimu, ati Naftuhimu; 12 Ati Patrusimu, ati Kasluhimu, (lati ọdọ ẹniti awọn ara Filistia ti ti wá) ati Kaftorimu. 13 Kenani si bi Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti; 14 Awọn ara Jebusi pẹlu, ati awọn ara Amori, ati awọn ara Girgaṣi; 15 Ati awọn ara Hifi, ati awọn ara Arki, ati awọn ara Sini; 16 Ati awọn ara Arfadi, ati awọn ara Semari, ati awọn ara Hamati. 17 Awọn ọmọ Ṣemu; Elamu, ati Aṣuri, ati Arfaksadi, ati Ludi, ati Aramu, ati Usi, ati Huli, ati Geteri, ati Meṣeki. 18 Arfaksadi si bi Ṣela, Ṣela si bi Eberi. 19 Ati fun Eberi li a bi ọmọkunrin meji: orukọ ekini ni Pelegi; nitori li ọjọ rẹ̀ aiye pin: orukọ arakunrin rẹ̀ si ni Joktani. 20 Joktani si bi Almodadi, ati Ṣelefu, ati Hasarmafeti, ati Jera; 21 Hadoramu pẹlu, ati Usali, ati Dikla; 22 Ati Ebali, ati Abimaeli, ati Ṣeba; 23 Ati Ofiri, ati Hafila, ati Jobabu. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Joktani. 24 Ṣemu, Arfaksadi, Ṣela; 25 Eberi, Pelegi, Reu; 26 Serugu, Nahori, Tẹra; 27 Abramu; Bakanna ni Abraham. 28 Awọn ọmọ Abraham; Isaaki, ati Iṣmaeli. 29 Wọnyi ni iran wọn: akọbi Iṣmaeli, Nebaioti; ati Kedari, ati Adbeeli, ati Mibsamu; 30 Miṣma, ati Duma, Massa, Hadadi, ati Tema; 31 Jeturi, Nafiṣi, ati Kedema. Wọnyi li awọn ọmọ Iṣmaeli. 32 Ati awọn ọmọ Ketura, obinrin Abrahamu: on bi Simrani, ati Jokṣani, ati Medani, ati Midiani, ati Iṣbaki, ati Ṣua. Ati awọn ọmọ Jokṣani; Ṣeba, ati Dedani. 33 Ati awọn ọmọ Midiani; Efa, ati Eferi, ati Henoku, ati Abida, ati Eldaa. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Ketura. 34 Abrahamu si bi Isaaki. Awọn ọmọ Isaaki; Esau ati Israeli. 35 Awọn ọmọ Esau; Elifasi, Reueli, ati Jeuṣi, ati Jaalamu, ati Kora. 36 Awọn ọmọ Elifasi; Temani, ati Omar, Sefi, ati Gatamu, Kenasi, ati Timna, ati Amaleki. 37 Awọn ọmọ Reueli; Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa.

38 Ati awọn ọmọ Seiri; Lotani, ati Ṣobali, ati Sibeoni, ati Ana, ati Disoni, ati Eseri, ati Diṣani. 39 Ati awọn ọmọ Lotani; Hori, ati Homamu: Timna si jẹ arabinrin Lotani. 40 Awọn ọmọ Ṣobali; Aliani, ati Manahat, ati Ebali, Ṣefi, ati Onamu. Ati awọn ọmọ Sibeoni; Aia, ati Ana. 41 Awọn ọmọ Ana; Dishon. Ati awọn ọmọ Disoni; Amramu, ati Eṣbani, ati Itrani, ati Kerani. 42 Awọn ọmọ Eseri; Bilhani, ati Zafani, ati Jakani. Awọn ọmọ Diṣani; Usi, ati Aran. 43 Njẹ wọnyi li awọn ọba ti o jọba ni ilẹ Edomu ki ọba ki o to jọba lori awọn ọmọ Israeli; Bela ọmọ Beori: orukọ ilu rẹ̀ si ni Dinhaba. 44 Nigbati Bela si kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra si jọba ni ipò rẹ̀. 45 Nigbati Jobabu si kú, Huṣamu ti ilẹ awọn ara Temani si jọba ni ipò rẹ̀. 46 Nigbati Huṣamu si kú, Hadadi ọmọ Bedadi, ti o kọlù Midiani ni oko Moabu, si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Afiti. 47 Nigbati Hadadi si kú, Samla ti Masreka si jọba ni ipò rẹ̀. 48 Nigbati Samla si kú, Ṣaulu ti Rehoboti leti odò si jọba ni ipò rẹ̀. 49 Nigbati Ṣaulu si kú, Baalhanani ọmọ Akbori si jọba ni ipò rẹ̀. 50 Nigbati Baalhanani si kú, Hadadi si jọba ni ipò rẹ̀: orukọ ilu rẹ̀ si ni Pai; Orukọ aya rẹ̀ si ni Mehetabeli, ọmọbinrin Matredi, ọmọbinrin Mesahabu. 51 Hádádì sì kú pẹ̀lú. Ati awọn olori Edomu ni; Timna olori, Aliah olori, Jeteti olori; 52 Ọba Aholibama, Ela olórí, Pinoni olórí; 53 Kenasi olori, Temani olori, Mibsari olori; 54 Duke Magdiel, olori Iram. Wọnyi li awọn ijoye Edomu. ORI 2 1 WỌNYI li awọn ọmọ Israeli; Reubeni, Simeoni, Lefi, ati Juda, Issakari, ati Sebuluni; 2 Dani, Josefu, ati Benjamini, Naftali, Gadi, ati Aṣeri. 3 Awọn ọmọ Juda; Eri, ati Onani, ati Ṣela: awọn mẹta ti a bi fun u lati ọdọ ọmọbinrin Ṣua ara Kenaani. Ati Eri, akọ́bi Juda, ṣe buburu li oju OLUWA; ó sì pa á. 4 Tamari aya ọmọ rẹ̀ si bí Faresi ati Sera fun u. Gbogbo àwọn ọmọ Juda jẹ́ marun-un. 5 Awọn ọmọ Faresi; Hesroni, ati Hamuli. 6 Ati awọn ọmọ Sera; Simri, ati Etani, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara: gbogbo wọn marun. 7 Ati awọn ọmọ Karmi; Ákárì, ẹni tí ń yọ Ísírẹ́lì lẹ́nu, ẹni tí ó ṣẹ̀ nínú ohun tí a yà sọ́tọ̀. 8 Ati awọn ọmọ Etani; Asaraya. 9 Awọn ọmọ Hesroni pẹlu, ti a bi fun u; Jerahmeeli, ati Ramu, ati Kelubai. 10 Ramu si bi Aminadabu; Aminadabu si bi Naṣoni, olori awọn ọmọ Juda; 11 Naṣoni si bi Salma, Salma si bi Boasi; 12 Boasi si bi Obedi, Obedi si bi Jesse; 13 Jesse si bi Eliabu akọbi rẹ̀, ati Abinadabu ekeji, ati Ṣimma ẹkẹta; 14 Netaneli ẹkẹrin, Radai ẹkẹrun. 15 Osemu ẹkẹfa, Dafidi ekeje. 16 Awọn arabinrin ẹniti iṣe Seruiah, ati Abigaili. Ati awọn ọmọ Seruia; Abiṣai, ati Joabu, ati Asaheli, mẹta.


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - The Book of 1st Chronicles by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu