Orin Solomoni ORI 1 1 ORIN awọn orin, ti iṣe ti Solomoni. 2 Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ fi ẹnu kò mi li ẹnu: nitoriti ifẹ rẹ san jù ọti-waini lọ. 3 Nitori õrùn ikunra rere rẹ li orukọ rẹ dabi ororo ikunra ti a dà jade, nitorina li awọn wundia ṣe fẹ ọ. 4 Fà mi, awa o sare tọ̀ ọ lẹhin: ọba ti mu mi wá si iyẹwu rẹ̀: awa o yọ̀, inu wa o si dùn si ọ, awa o ranti ifẹ rẹ jù ọtiwaini lọ: awọn olododo fẹ ọ. 5 Emi dudu, ṣugbọn arẹwà, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi agọ Kedari, bi aṣọ-tita Solomoni. 6 Máṣe wò mi, nitoriti emi dudu, nitoriti õrun ti wò mi: awọn ọmọ iya mi binu si mi; wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà; ṣugbọn ọgba-ajara temi li emi kò tọju. 7 Sọ fun mi, iwọ ẹniti ọkàn mi fẹ́, nibiti iwọ njẹ, nibiti iwọ mu agbo-ẹran rẹ simi li ọsangangan: nitori ẽṣe ti emi o fi dabi ẹniti o yà lẹba agbo-ẹran awọn ẹlẹgbẹ rẹ? . 9 Olufẹ mi, emi ti fi ọ wé ẹgbẹ́ ẹṣin ninu kẹkẹ́ Farao. 10 Ẹrẹkẹ rẹ li ẹwà pẹlu ọ̀wọ́ ohun-ọṣọ, ọrùn rẹ pẹlu ẹ̀wọn wura. 11 A óo fi wúrà þe ðnà fàdákà. 12 Nigbati ọba ba joko ni tabili rẹ̀, nardi mi si rán õrùn rẹ̀ jade. 13 Idi ojia li olufẹ mi si mi; gbogbo òru ni yóò dùbúlẹ̀ láàrin ọmú mi. 14 Olufẹ mi ri si mi bi ìdi-ìdi-iṣu-ọgbà-àjara ti Engedi. 15 Kiyesi i, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; kiyesi i, iwọ li ẹwà; iwọ li oju àdaba. 16 Kiyesi i, iwọ li ẹwà, olufẹ mi, nitõtọ, o dùn: pẹlu li akete wa tutu. 17 Igi kedari ni igi ile wa, ati igi firi wa. ORI 2 1 EMI ni ododo Ṣaroni, ati itanna lili afonifoji. 2 Bi itanna lili lãrin ẹgún, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọbinrin. 3 Bi igi apple lãrin igi igbó, bẹ̃li olufẹ mi ri lãrin awọn ọmọ. Mo jókòó lábẹ́ òjìji rẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńlá, èso rẹ̀ sì dùn sí mi. 4 Ó mú mi wá sí ilé àsè, ìfẹ́ sì ni àsíá rẹ̀ lórí mi. . 6 Ọwọ́ òsi rẹ̀ mbẹ labẹ ori mi, ọwọ ọtún rẹ̀ si gbá mi mọra. 7 Mo fi àgbọ̀nrín àti àgbọ̀nrín ìgbẹ́ kìlọ̀ fún yín, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù,kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ mi sókè tàbí jí i títí yóò fi wù ú. 8 Ohùn olufẹ mi! wò o, o mbọ̀ wá, o nfò lori awọn òke nla, o nfò lori awọn òke nla. . 10 Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi, ki o si jade lọ. 11 Nitori kiyesi i, igba otutu ti kọja, òjo si tan, o si ti lọ; 12 Awọn itanna han lori ilẹ; Àkókò tí àwọn ẹyẹ ń kọrin dé, a sì gbọ́ ohùn ìpadàlẹ̀ ní ilẹ̀ wa; 13 Igi ọ̀pọtọ so eso ọ̀pọtọ tutù jade, ati àjara pẹlu eso-àjara tutu mu õrùn didùn. Dide, olufẹ mi, arẹwa mi, ki o si lọ.
14 Àdàbà mi, tí ó wà ní pàlàpálá àpáta,ní ibi ìkọ̀kọ̀ àtẹ̀gùn,jẹ́ kí n rí ojú rẹ,jẹ́ kí n gbọ́ ohùn rẹ; nitoriti ohùn rẹ dùn, oju rẹ si li ẹwà. 15 Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékèké, ti o ba àjara jẹ́: nitori àjara wa ni eso-àjara tutu. 16 Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o jẹ ninu awọn lili. 17 Titi ilẹ fi mọ, ti ojiji yio fi lọ, yipada, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi egbin tabi ọmọ agbọnrin lori awọn òke Beteri. ORI 3 1 LORI akete mi li alẹ mo wá ẹniti ọkàn mi fẹ: mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i. . 3 Awọn oluṣọ ti nrìn kiri ilu na ri mi: ẹniti mo wi fun pe, Ẹ ha ri ẹniti ọkàn mi fẹ? 4 Ni diẹ ni mo kọja lọdọ wọn, ṣugbọn mo ri ẹniti ọkàn mi fẹ: emi dì a mu, emi kò si jẹ ki o lọ, titi emi o fi mu u wá si ile iya mi, ati sinu iyẹwu ẹniti o bi mi. 5 Mo fi àgbọ̀nrín àti àgbọ̀nrín ìgbẹ́ kìlọ̀ fun yín, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù pé kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ mi sókè, ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú. 6 Tani eyi ti o ti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẹ̃fin, ti a fi ojia ati turari di turari, pẹlu gbogbo erupẹ oniṣòwo? 7 Kiyesi i akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akikanju ọkunrin ti o wà yi i ka, ninu awọn akọni Israeli. 8 Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn mọ̀ ogun: olukuluku li idà rẹ̀ li itan rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru. 9 Solomoni ọba fi igi Lẹbanoni ṣe kẹ̀kẹ́ ogun fún ara rẹ̀. 10 Ó fi fadaka ṣe àwọn òpó rẹ̀,ó fi wúrà ṣe ìsàlẹ̀ rẹ̀,ó fi elése àlùkò ṣe ìbòrí rẹ̀,a sì fi ìfẹ́ ṣe ààrin rẹ̀ fún àwọn ọmọbinrin Jerusalẹmu. 11 Ẹ jade lọ, ẹnyin ọmọbinrin Sioni, si wò Solomoni ọba, ti on ti ade ti iya rẹ̀ fi de e li ade li ọjọ́ oko rẹ̀, ati li ọjọ ayọ̀ ọkàn rẹ̀. ORI 4 1 Kiyesi i, iwọ li ẹwà, olufẹ mi; kiyesi i, iwọ li ẹwà; iwọ li oju àdaba ninu ìdidi rẹ: irun rẹ dabi agbo ewurẹ, ti o farahan lati òke Gileadi. . ninu eyiti olukuluku bi ìbejì, kò si si ẹniti o yàgan ninu wọn. 3 Ètè rẹ dàbí òwú òdòdó, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì lẹ́wà; 4 Ọrùn rẹ dabi ile-iṣọ Dafidi ti a kọ́ fun ile-ihamọra, lori eyiti a fi ẹgbẹrun apata kọ́, gbogbo asà awọn alagbara akọni. 5 Ọmú rẹ mejeji dabi ọmọ àgbọ̀nrin meji ti iṣe ìbejì, ti njẹ lãrin itanna lili. 6 Titi ilẹ fi mọ, ti ojiji yio fi fò lọ, emi o mu mi lọ si ori òke ojia, ati si òke turari. 7 Iwọ li ẹwà gbogbo, olufẹ mi; ko si aaye ninu rẹ. . 9 Iwọ ti yọ̀ mi li ọkàn, arabinrin mi, iyawo mi; iwọ ti fi ọ̀kan ninu oju rẹ mú ọkàn mi yọ̀, pẹlu ẹ̀wọn ọrùn rẹ kan. 10 Bawo ni ifẹ rẹ ti dara to, arabinrin mi, iyawo mi! melomelo ni ifẹ rẹ ti san jù ọti-waini lọ! ati õrùn ikunra rẹ ju gbogbo turari lọ! 11 11 Ete rẹ, iyawo mi, ma rẹ̀ silẹ bi afárá oyin: oyin ati wàra mbẹ labẹ ahọn rẹ; òórùn aṣọ rẹ sì dàbí òórùn Lẹ́bánónì. 12 Ọgbà kan ti a ti pati ni arabinrin mi, iyawo mi; orisun kan ti a ti pa, ti a fi edidi kan orisun.