Skip to main content

Yoruba - Biblical Polygamy

Page 1

Ìgbéyàwó Oníyàwó Púpọ̀ Nínú Bíbélì Lameki sì fẹ́ ìyàwó méjì fún un: orúkọ ọ̀kan ni Ada, orúkọ èkejì sì ni Silla. Genesisi 4:19 Bí ó bá fẹ́ ìyàwó mìíràn fún un; oúnjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, àti ẹrù ìgbéyàwó rẹ̀, kò gbọdọ̀ dínkù. Bí kò bá sì ṣe àwọn mẹ́ta wọ̀nyí fún un, nígbà náà ni kí ó jáde lọ láìsí owó. Ẹ́ kísódù 21:10-11 Bí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, ọ̀kan tí ó fẹ́ràn, tí òmíràn sì kórìíra, tí wọ́n sì bí ọmọ fún un, àti olùfẹ́ àti ẹni tí a kórìíra; àti bí àkọ́bí ọmọkùnrin bá jẹ́ tirẹ̀ tí a kórìíra: Nígbà náà ni yóò jẹ́, nígbà tí ó bá fi àwọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun tí ó ní, kí ó má ṣe fi ọmọ àkọ́bí olùfẹ́ hàn níwájú ọmọ ẹni tí a kórìíra, èyí tí í ṣe àkọ́bí ní tòótọ́: Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́wọ́ ọmọ ẹni tí a kórìíra gẹ́gẹ́ bí àkọ́bí, nípa fífún un ní ìpín méjì nínú gbogbo ohun tí ó ní: nítorí òun ni ìbẹ̀rẹ̀ agbára rẹ̀; ẹ̀tọ́ àkọ́bí ni tirẹ̀. Deuteronomi 21:15-17 Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn sì kú, tí kò sì ní ọmọ, aya òkú kò gbọdọ̀ fẹ́ àlejò ní òde: arákùnrin ọkọ rẹ̀ gbọdọ̀ wọlé tọ̀ ọ́, kí ó sì mú un ṣe aya rẹ̀, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ rẹ̀ sí i. Yóò sì ṣe pé, àkọ́bí tí ó bí yóò gba ipò rẹ̀ ní orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó ti kú, kí orúkọ rẹ̀ má baà parẹ́ ní Israẹli. Bí ọkùnrin náà kò bá sì fẹ́ gba ìyàwó arákùnrin rẹ̀, nígbà náà ni kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ gòkè lọ sí ẹnu ibodè sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà, kí ó sì wí pé, “Arákùnrin ọkọ mi kọ̀ láti gbé orúkọ kan dìde fún arákùnrin rẹ̀ ní Israẹli, kò ní ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ mi.” Nígbà náà ni àwọn àgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá a sọ̀rọ̀: bí ó bá sì dúró sí i, tí ó sì wí pé, “Èmi kò fẹ́ gbà á.” Nígbà náà ni aya arákùnrin rẹ̀ yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ níwájú àwọn àgbàgbà, yóò sì bọ́ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, yóò sì tutọ́ sí ojú rẹ̀, yóò sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ọkùnrin náà tí kò bá kọ́ ilé arákùnrin rẹ̀.” A ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Israẹli ní ilé ẹni tí ó bọ́ bàtà rẹ̀. Deuteronomi 25:5-10 Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje yóò di ọkùnrin kan mú, wọn yóò wí pé, “Àwa yóò jẹ oúnjẹ tiwa, a ó sì wọ aṣọ tiwa: ṣùgbọ́n jẹ́ kí a fi orúkọ rẹ pè wá, láti mú ẹ̀gàn wa kúrò.” Isaiah 4:1

1


Ìgbéyàwó Oníyàwó Púpọ̀ Nínú Bíbélì

Ábúráhámù Abramu àti Nahori sì fẹ́ aya fún wọn: orúkọ aya Abramu ni Sarai; orúkọ aya Nahori sì ni Milka, ọmọbìnrin Harani, baba Milka, àti baba Iska. Genesisi 11:29 Sarai aya Abramu kò bímọ fún un: ó sì ní ìránṣẹ́bìnrin kan, ará Egipti, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari. Sarai sì wí fún Abramu pé, “Wò ó, Olúwa ti dá mi dúró láti bímọ: mo bẹ̀ ọ́, wọlé tọ ìránṣẹ́bìnrin mi lọ; bóyá kí n lè ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Abramu sì gbọ́ ohùn Sarai. Sarai aya Abramu sì mú Hagari ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ará Egipti, lẹ́yìn tí Abramu ti gbé ní ilẹ̀ Kenaani fún ọdún mẹ́wàá, ó sì fi í fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti jẹ́ aya rẹ̀. Ó sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún: nígbà tí ó sì rí i pé ó lóyún, a fi ojú tẹmbẹlu ìyá rẹ̀. Genesisi 16:1-4 Lẹ́yìn náà, Ábúráhámù tún fẹ́ ìyàwó kan, orúkọ rẹ̀ sì ni Kétúrà. Ó sì bí Símíránì, Jókíṣánì, Médánì, Mídíánì, Íṣíbákì, àti Ṣúà. Jókíṣánì sì bí Ṣébà, àti Dédánì. Àwọn ọmọ Dédánì sì ni Áṣúrímù, Létúṣímù, àti Léúmímù. Àwọn ọmọ Mídíánì sì ni Éfà, àti Éférì, àti Hánókì, àti Ábídà, àti Élídáà. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kétúrà. Ábúráhámù sì fi gbogbo ohun tí ó ní fún Ísáákì. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ àwọn obìnrin tí Ábúráhámù ní, Ábúráhámù fún wọn ní ẹ̀bùn, ó sì rán wọn lọ kúrò lọ́dọ̀ Ísáákì ọmọ rẹ̀, nígbà tí ó ń gbé ní ìlà-oòrùn, sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn. Jẹ́nẹ́sísì 25:1-6

Esau Ísọ̀ sì jẹ́ ẹni ogójì ọdún nígbà tí ó fẹ́ Júdítì ọmọbìnrin Béérì ará Hítì àti Báṣémátì ọmọbìnrin Élónì ará Hítì fún aya: èyí tí ó jẹ́ ìbànújẹ́ ọkàn fún Ísákì àti Rèbékà. Jẹ́nẹ́sísì 26:34-35 Nígbà náà ni Esau lọ sí ọ̀dọ̀ Iṣmaeli, ó sì fẹ́ Mahalati ọmọbìnrin Iṣmaeli ọmọ Abrahamu, arábìnrin Nebajoti, pẹ̀lú àwọn aya tí ó ní. Genesisi 28:9 Àwọn wọ̀nyí ni ìran Esau, ẹni tí í ṣe Edomu. Ísọ̀ fẹ́ àwọn ìyàwó rẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin Kénáánì; Ádà ọmọbìnrin Élónì ará Hítì àti Áhólíbámà ọmọbìnrin Áná, ọmọbìnrin Síbéónì ará Hífì. Àti ọmọbìnrin Baṣemati Iṣmaeli, arábìnrin Nebajoti. Jẹ́nẹ́sísì 36:1-3

Jákọ́bù Jakọbu sì wí fún Labani pé, “Fún mi ní aya mi, nítorí ọjọ́ mi ti pé, kí èmi lè bá a lòpọ̀.” Labani sì pe gbogbo àwọn ọkùnrin ibẹ̀ jọ, ó sì se àsè. Ó sì ṣe ní alẹ́, ó mú Lea ọmọbìnrin rẹ̀, ó sì mú un wá fún un, òun sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ. Labani sì fi Silpa, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fún Lea, ọmọbìnrin rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́bìnrin. Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, nígbà tí ó di òwúrọ̀, ó rí i pé Lea ni. Ó sì wí fún Labani pé, “Kí ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Ṣé èmi kò sìn ọ́ fún Rakeli? Èéṣe tí ìwọ fi tàn mí jẹ?” Labani sì wí pé, “Kò yẹ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ wa, láti fún àbúrò ní ẹ̀bùn ṣáájú àkọ́bí.” Ṣe ọ̀sẹ̀ rẹ̀ tán, àwa yóò sì fún ọ ní èyí pẹ̀lú fún iṣẹ́ ìsìn tí ìwọ yóò ṣe fún mi ní ọdún méje mìíràn. Jakọbu sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì parí ọ̀sẹ̀ rẹ̀: ó sì fi Rakeli ọmọbìnrin rẹ̀ fún un ní aya pẹ̀lú. Labani sì fi Bilha, ọmọ-ọdọ rẹ̀, fún Rakeli, ọmọbìnrin rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó sì bá Rakeli lòpọ̀ pẹ̀lú, ó sì fẹ́ràn Rakeli ju Lea lọ, ó sì tún sìn ín fún ọdún méje mìíràn. Jẹ́nẹ́sísì 29:21-30 Nígbà tí Rakeli rí i pé òun kò bímọ fún Jakọbu, Rakeli ṣe ìlara arábìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jakọbu pé, “Fún mi ní ọmọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, èmi yóò kú.” Inú bí Jékọ́bù sí Rákẹ́lì, ó sì wí pé, “Ṣé èmi wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ fún ọ láti jẹ èso inú?” Ó sì wí pé, “Wò ó, Bilha ìránṣẹ́bìnrin mi, wọlé tọ̀ ọ́, yóò sì bímọ lórí eékún mi, kí èmi pẹ̀lú lè ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” Ó sì fún un ní Bilha ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya: Jakọbu sì bá a lòpọ̀. Jẹ́nẹ́sísì 30:1-4

2


Ìgbéyàwó Oníyàwó Púpọ̀ Nínú Bíbélì

Nígbà tí Lea rí i pé òun ti dẹ́kun ìbímọ, ó mú Silpa, iranṣẹbinrin rẹ̀, ó sì fún Jakọbu ní aya. Jẹ́nẹ́sísì 30:9

Gideoni Gideoni sì ní àádọ́rin ọmọ tí a bí fún un: nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya. Àle rẹ̀ tí ó wà ní Ṣekemu sì bí ọmọkùnrin kan fún un, orúkọ rẹ̀ ni Abimeleki. Àwọn Onídàájọ́ 8:30-31

Jairi Lẹ́yìn rẹ̀ ni Jairi, ará Gileadi dìde, ó sì ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méjìlélógún. Ó sì ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì ní ọgbọ̀n ìlú, tí a ń pè ní Hafoth Jairi títí di òní, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi. Àwọn Onídàájọ́ 10:3-4

Íbsánì Lẹ́yìn rẹ̀, Ibsani ará Bẹtilẹhẹmu ṣe ìdájọ́ Israẹli. Ó sì ní ọgbọ̀n ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọbìnrin, àwọn tí ó rán lọ síta, ó sì fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbìnrin láti òkèèrè fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ó sì ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún méje. Àwọn Onídàájọ́ 12:8-9

Abdon Lẹ́yìn rẹ̀, Abdoni ọmọ Hillel, ará Piratoni, ṣe ìdájọ́ Israẹli. Ó sì ní ogójì ọmọkùnrin àti ọgbọ̀n ọmọkùnrin, tí wọ́n ń gun ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àádọ́rin: ó sì ṣe ìdájọ́ Israẹli fún ọdún mẹ́jọ. Àwọn Onídàájọ́ 12:13-14

Ẹlikénà Ọkunrin kan wà láti Ramataimsofimu, láti òkè Efraimu, orúkọ rẹ̀ sì ni Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elihu, ọmọ Tohu, ọmọ Sufu, ará Efrata. Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ ọ̀kan ni Hana, orúkọ èkejì sì ni Penina. Penina bí ọmọ, ṣùgbọ́n Hana kò bímọ. Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọọdun lati sìn ati lati rubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Awọn ọmọ Eli meji, Hofni ati Finehasi, awọn alufa Oluwa, si wà nibẹ. Nígbà tí àkókò tí Elkana fi rúbọ náà tó, ó fún Penina ní ìpín fún aya rẹ̀, àti fún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin. Ṣùgbọ́n ó fún Hana ní ìpín tí ó yẹ; nítorí ó fẹ́ràn Hana: ṣùgbọ́n Olúwa ti sé ilé rẹ̀. Ọ̀tá rẹ̀ náà sì ń yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi, nítorí pé ó fẹ́ mú un bínú, nítorí pé Olúwa ti sé ilé ọmọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún, nígbà tí ó bá gòkè lọ sí ilé Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni ó ń mú un bínú; nítorí náà ó ń sọkún, kò sì jẹun. Nígbà náà ni Elkana ọkọ rẹ̀ wí fún un pé, “Hana, kí ló dé tí o fi ń sunkún, kí ló dé tí o kò fi jẹun, kí ló dé tí ọkàn rẹ fi bàjẹ́? Ṣé èmi kò sàn ju ọmọ mẹ́wàá lọ fún ọ?” 1 Samuẹli 1:1-8

Saulu Orúkọ aya Saulu sì ni Ahinoamu, ọmọbìnrin Ahimaasi … 1 Samuẹli 14:50 Saulu ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah… 2 Samuẹli 3:7

3


Ìgbéyàwó Oníyàwó Púpọ̀ Nínú Bíbélì

Dáfídì Nítorí náà, Dáfídì dìde, ó sì lọ, òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀, ó sì pa ọgọ́rùn-ún méjì ọkùnrin nínú àwọn ará Fílístínì; Dáfídì sì mú adọ̀dọ́ wọn wá, wọ́n sì fi gbogbo wọn fún ọba, kí ó lè jẹ́ ọkọ ọba. Ṣọ́ọ̀lù sì fi Míkálì ọmọbìnrin rẹ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí aya. 1 Sámúẹ́lì 18:27 Abigaili sì yára dìde, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ márùn-ún tí wọ́n tẹ̀lé e, ó sì tẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, ó sì di aya rẹ̀. Dafidi sì mú Ahinoamu ará Jesreeli pẹ̀lú; àwọn méjèèjì sì jẹ́ aya rẹ̀. 1 Samuẹli 25:42-43 Àwọn ọmọ Dafidi ni a bí ní Hebroni: Àkọ́bí rẹ̀ ni Amnoni, ọmọ Ahinoamu ará Jesreeli; àti èkejì rẹ̀ ni Kileabu, ọmọ Abigaili aya Nabali ará Karmeli; àti ẹ̀kẹta, Absalomu ọmọ Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri; àti ẹ̀kẹrin, Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀kẹrin, Ṣefatia ọmọ Abitali; àti ẹ̀kẹfà, Itreamu, ọmọ Egla aya Dafidi. Àwọn wọ̀nyí ni a bí fún Dafidi ní Hebroni. 2 Samuẹli 3:2-5 Dáfídì sì mọ̀ pé Olúwa ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ọba lórí Ísírẹ́lì, àti pé ó ti gbé ìjọba rẹ̀ ga nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì. Dáfídì sì mú àwọn àlè àti aya mìíràn láti Jerúsálẹ́mù, lẹ́yìn tí ó ti Hébúrónì dé: àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin sì tún bí fún Dáfídì. 2 Sámúẹ́lì 5:12-13 Nígbà tí aya Uria gbọ́ pé Uria ọkọ rẹ̀ ti kú, ó ṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀. Nígbà tí ìbànújẹ́ náà sì parí, Dafidi ranṣẹ sí i, ó sì mú un wá sí ilé rẹ̀, ó sì di aya rẹ̀, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. Ṣugbọn ohun tí Dafidi ṣe kò dùn mọ́ OLUWA. 2 Samuẹli 11:26-27 Nátánì sì wí fún Dáfídì pé, “Ìwọ ni ọkùnrin náà.” Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “Èmi fi ọ́ ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì, mo sì gbà ọ́ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.” Mo sì fi ilé ọ̀gá rẹ fún ọ, àti àwọn ìyàwó ọ̀gá rẹ sí àyà rẹ, mo sì fi ilé Ísírẹ́lì àti ti Júdà fún ọ; bí ó bá sì kéré jù, èmi ìbá tún fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fún ọ. Kí ló dé tí o fi kẹ́gàn àṣẹ Olúwa, láti ṣe ibi ní ojú rẹ̀? Ìwọ ti fi idà pa Ùráyà ará Hítì, o sì ti mú ìyàwó rẹ̀ láti ṣe aya rẹ, o sì ti fi idà àwọn ọmọ Ámónì pa á. 2 Sámúẹ́lì 12:7-9 Ọba sì jáde lọ, gbogbo ilé rẹ̀ sì tẹ̀lé e. Ọba sì fi àwọn obìnrin mẹ́wàá sílẹ̀, àwọn àlè, láti máa ṣọ́ ilé. 2 Samuẹli 15:16 Dáfídì sì dé ilé rẹ̀ ní Jérúsálẹ́mù; ọba sì mú àwọn obìnrin mẹ́wàá tí ó fi sílẹ̀ láti máa ṣọ́ ilé, ó sì fi wọ́n sí àhámọ́, ó sì ń bọ́ wọn, ṣùgbọ́n kò wọlé tọ̀ wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe wà ní àhámọ́ títí di ọjọ́ ikú wọn, wọ́n sì ń gbé gẹ́gẹ́ bí opó. 2 Sámúẹ́lì 20:3

Sólómọ́nì Ṣùgbọ́n ọba Solomoni fẹ́ràn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin àjèjì, pẹ̀lú ọmọbìnrin Farao, àwọn obìnrin ará Moabu, Ammoni, Edomu, Sidoni àti àwọn ará Hitti; Nínú àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ wọlé tọ wọ́n lọ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ wọlé tọ yín lọ, nítorí dájúdájú wọn yóò yí ọkàn yín padà sí àwọn ọlọ́run wọn.” Sólómónì fà mọ́ àwọn wọ̀nyí ní ìfẹ́. Ó sì ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ìyàwó, àwọn ọmọ ọba, àti ọ̀ọ́dúnrún àwọn àlè: àwọn aya rẹ̀ sì yí ọkàn rẹ̀ padà. Nítorí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Solomoni di arúgbó, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí ọkàn rẹ̀ padà sí àwọn ọlọ́run mìíràn: ọkàn rẹ̀ kò sì pé pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọkàn Dafidi baba rẹ̀ ti rí. Nítorí pé Sólómónì tẹ̀lé Ásítórétì òrìṣà àwọn ará Sídónì, àti Mílíkómù ohun ìríra àwọn ará Ámónì. Sólómónì sì ṣe búburú níwájú Olúwa, kò sì tẹ̀lé Olúwa ní kíkún bí Dáfídì baba rẹ̀ ti ṣe. Nígbà náà ni Solomoni kọ́ ibi gíga kan fún Kemoṣi, ohun ìríra Moabu, ní òkè tí ó wà níwájú Jerusalẹmu, àti fún Moleki, ohun ìríra àwọn ọmọ Ammoni. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣe fún gbogbo àwọn ìyàwó àjèjì rẹ̀, àwọn tí wọ́n ń sun tùràrí tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn òrìṣà wọn. 4


Ìgbéyàwó Oníyàwó Púpọ̀ Nínú Bíbélì

Olúwa sì bínú sí Solomoni, nítorí ọkàn rẹ̀ yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti farahàn án lẹ́ẹ̀méjì. Ó sì ti pàṣẹ fún un nípa èyí pé kí ó má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn: ṣùgbọ́n kò pa àṣẹ Olúwa mọ́. 1 Àwọn Ọba 11:1-10

Rèhóbóámù Rehoboamu fẹ́ Mahalati, ọmọbìnrin Jerimoti, ọmọ Dafidi, àti Abihaili, ọmọbìnrin Eliabu, ọmọ Jesse. Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jeuṣi, Ṣamariah àti Sahamu. Lẹ́yìn rẹ̀, ó fẹ́ Maaka ọmọbìnrin Absalomu, ẹni tí ó bí Abijah, Attai, Sisa àti Ṣelomiti fún un. Rèhóbóámù fẹ́ràn Máákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju gbogbo àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ lọ (nítorí ó fẹ́ ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè; ó sì bí ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin). 2 Kíróníkà 11:18-21

Abijah Ṣùgbọ́n Abijah di alágbára, ó sì fẹ́ ìyàwó mẹ́rìnlá, ó sì bí ọmọkùnrin méjìlélógún, àti ọmọbìnrin mẹ́rìndínlógún. 2 Kronika 13:21

Ahabu Bẹ́nhádádì ọba Síríà kó gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ jọ, àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin: ó sì gòkè lọ sí Samáríà, ó sì bá a jà. Ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Áhábù ọba Ísírẹ́lì sínú ìlú náà, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Bẹ́nhádádì wí, Fàdákà àti wúrà rẹ jẹ́ tèmi; àwọn ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú, àní àwọn tí ó dára jùlọ, jẹ́ tèmi.” Ọba Ísírẹ́lì sì dáhùn ó sì wí pé, “Olúwa mi, ọba, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, èmi ni tìrẹ, àti gbogbo ohun tí mo ní.” Àwọn ìránṣẹ́ náà sì padà wá, wọ́n sì wí pé, “Báyìí ni Bẹ́nhádádì wí, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ránṣẹ́ sí ọ pé, ‘Ìwọ yóò fi fàdákà rẹ àti wúrà rẹ fún mi, àwọn ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ; ṣùgbọ́n èmi yóò rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ ní àkókò yìí lọ́la, wọn yóò sì ṣe àwárí ilé rẹ àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ; yóò sì ṣe pé, ohunkóhun tí ó bá dára lójú rẹ, wọn yóò fi sí ọwọ́ wọn, wọn yóò sì gbà á lọ.’” Nígbà náà ni ọba Ísírẹ́lì pe gbogbo àwọn àgbà ilẹ̀ náà, ó sì wí pé, “Ẹ kíyèsí i, mo bẹ̀ yín, ẹ wo bí ọkùnrin yìí ṣe ń wá ibi: nítorí ó ránṣẹ́ sí mi fún àwọn aya mi, àti fún àwọn ọmọ mi, àti fún fàdákà mi, àti fún wúrà mi; èmi kò sì sẹ́ ẹ.” Gbogbo àwọn àgbà àti gbogbo ènìyàn sì wí fún un pé, “Má ṣe fetí sí i, má sì ṣe gbà.” 1 Àwọn Ọba 20:1-8 Ahabu sì ní àádọ́rin ọmọ ní Samaria… 2 Àwọn Ọba 10:1

Jóásì Ọmọ ọdún méje ni Joaṣi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá rẹ̀ náà ni Sibia ará Beerṣeba. Joaṣi sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọjọ́ Jehoiada àlùfáà. Jehoiada sì fẹ́ ìyàwó méjì fún un, ó sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. 2 Kronika 24:1-3

5


Turn static files into dynamic content formats.

Create a flipbook
Yoruba - Biblical Polygamy by Filipino Tracts and Literature Society Inc. - Issuu